Ile-ẹjọ ti da ẹjọ ti Atiku pe Tinubu nu

Faith Adebọla

Ẹjọ kan, ti oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar, pe ta ko Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, nile-ẹjọ giga Circuit Court of Cook County, to fikalẹ siluu Illinois, lorileede Amẹrika lọhun-un, ti fori ṣanpọn. Atiku ti loun ko ṣẹjọ naa mọ, n nile-ẹjọ ba da ẹjọ ọhun nu bii omi iṣanwọ.

Atẹjade kan tiweeroyin Gatekeepers News, tilẹ Amẹrika, fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ yii, ṣalaye pe Atiku lo parọwa si kootu naa pe ki wọn ba oun faṣẹ si i, ki wọn si kan an nipa fun Fasiti ipinlẹ Chicago, iyẹn Chicago State University, USA, lati pese ẹri ati ẹda iwe-ẹri lati fidi rẹ mulẹ boya loootọ ni Aarẹ Tinubu kawe yọri lọdọ wọn, to ba si jẹ bẹẹ, ki wọn ko gbogbo akọsilẹ igba ti Tinubu wọle sileewe wọn, igba to ṣedanwo, igba to ṣe tẹẹṣi, esi idanwo rẹ lati ibẹrẹ ẹkọ rẹ de ipari ati bẹẹ bẹẹ lọ jade.

Ẹ oo ranti pe lasiko ipolongo ibo, Tinubu to n ṣoju fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti sọ pe Yunifasiti Chicago yii loun ti kawe gboye ninu imọ nipa okoowo (Business Administration).

Agbẹjọro kan nilẹ naa, Ọgbẹni Victor Henderson, sọ pe ko sẹni ti ko mọ pe ọpọ awọn olugbe ilu Illinois lo mọ Tinubu bii ẹni mowo, ti wọn si mọ pe loootọ lo kawe jade ni fasiti ti wọn n sọrọ rẹ yii.

Wọn ni ko ju ọsẹ meji lẹyin to pe Tinubu lẹjọ tan lo tun pe awọn alaṣẹ fasiti naa lati waa wi tẹnu wọn. Kile-ẹjọ naa too mu ọjọ ti igbẹjọ yoo bẹrẹ ni Atiku ṣẹri pada biri, o lọ sile-ẹjọ naa pe oun ko ṣẹjọ mọ, o ni ki wọn wọgi le ẹbẹ ati ẹjọ toun pe ọhun, fun idi kan toun ko fẹẹ sọ sita.

Lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, iyẹn ọjọ Aje, ọsẹ to kọja, ni Onidaajọ Patrick J. Heneghan, da ẹjọ naa nu, to si fa iwe ipẹjọ Atiku Abubakar ya, nigba to ti loun ko ṣẹjọ mọ.

Ninu akọsilẹ to wa ni kootu ọhun, Adajọ Heneghan ni, “ile-ẹjọ ko ti i bẹrẹ igbẹjọ lati pinnu boya ẹjọ to lẹsẹ nilẹ ni abi bẹẹ kọ, boya a maa gba ẹbẹ olupẹjọ wọle abi a o ni i gba a, amọ a ti wọgi le ẹjọ yii gẹgẹ bii ibeere olupẹjọ yii.”

Leave a Reply