Ile-ẹjọ ti gba beeli Farotimi, eyi lawọn ohun to gbọdọ ṣe

Surdiq Taofeek, Ado-Ekiti

 

Fọfọọfọ ni ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, nibi ti igbẹjọ ti waye lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan lọọya to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Dele Farotimi, lori awọn ọrọ ibanilorukọ jẹ kan ti wọn lo kọ sinu iwe kan to ṣe nipa agba lọọya nni, Afẹ Babalaọla, kun lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu yii.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ni wọn gbe ọkunrin ajafẹtọọ ọmọniyan naa de kootu. Bo ṣe bọọlẹ ninu ọkọ ọgba ẹwọn ti wọn fi gbe e wa ni awọn ajafẹtọọ atawọn ọdọ ti wọn kun inu ọgba kootu naa fọfọ ti wọn ti n duro de e ti bẹrẹ si i ki i, ti wọn n sa a, ti wọn si n sọ awọn ede ti wọn maa n sọ fun awọn ẹgbẹ wọn to jẹ ajijagbara, bẹẹ ni wọn n kọrin.

Ọkunrin to wọ aṣọ ṣaati pupa naa bẹrẹ si i juwọ si wọn, to si n ki awọn ẹlẹgbẹ rẹ yii.

Niṣe ni awọn agbofinro pagbo yi i ka, ti wọn si sin in wọnu kootu ti igbẹjọ naa ti waye.

Beeli miliọnu lọna ọgbọn Naira ni Onidaajọ Abayọmi Adeọṣun fun Farotimi. Yatọ si beeli ti wọn fun un yii, o gbọdọ wa oniduuro mẹta ti wọn gbọdọ ni ilẹ ni agbegbe ile-ẹjọ. Bakan naa ni ile-ẹjọ paṣẹ pe ọkunrin ajafẹtọọ ọmọniyan to mu lẹnu bii abẹ naa gbọdọ fi iwe irinna rẹ s’Oke-Okun silẹ, bẹẹ ni ko gbọdọ ba oniroyin kankan sọrọ  bo ba jade tan.

Bẹ o ba gbagbe, ẹsun mẹrinla ọtọọtọ ni awọn ọlọpaa fi kan ọkunrin yii nigba ti wọn kọkọ gbe e wa sile-ẹjọ. Lara rẹ ni ibanilorukọjẹ, ṣugbọn ti Farotimi ni oun ko jẹbi.

Ile-ẹjọ kọ lati gba beeli rẹ nigba naa, ti adajọ si paṣẹ pe ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu yii, ni igbẹjọ mi-in tun waye, ti kootu si fun un ni beeli pẹlu oniduuro mẹta.

Tẹ o ba gbagbe, iwe kan, ‘Criminal Justice System’ ni agbẹjọro naa kọ, nibi to ti naka abuku si agbalagba lọọya to ni ileewe Afẹ Babalọla Yunifasiti nni, Alagba Afẹ Babalọla, pe o lo ipo rẹ lati yi eto idajọ kan pada nipa lilo awọn adajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa atawọn ẹsun mi-in.

Eyi lo mu ki baba naa gbe e lọ sile-ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ, to si ti tun kọwe ranṣẹ si ajọ to n ri si ọrọ awọn agbẹjọro pe ki wọn yọ orukọ Farotimi kuro ninu awọn agbẹjọro lorileede yii.

Ilu Eko ni wọn ti lọọ gbe ọkunrin naa ni nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin, to si ti n jẹjọ latigba naa. Lasiko igbẹjọ akọkọ ni wọn ni ki wọn da a pada si ọgba ẹwọn, ti wọn si sun igbẹjọ si ogunjọ, oṣu yii.

Aarọ ọjọ Ẹti ni wọn fun Farotimi ni beeli. Lẹyin eyi ni Onidaajọ Abayọmi Adeọṣun sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun to n bọ.

Leave a Reply