Ile-ẹjọ to ga ju lọ da ẹjọ ti ẹgbẹ PDP ta ko gomina Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gbogbo akitiyan ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ẹka tipinlẹ Kwara, pe ki ile-ẹjọ paṣẹ fun ajọ eleto idibo ko yọ orukọ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq kuro lara awọn oludije dupo gomina nipinlẹ naa nibi eto idibo apapọ ọdun 2023, fun ẹsun pe ayederu iwe-ẹri lo gbe kalẹ fun ajọ naa lo ja si pabo pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe da ẹjọ naa nu.

Ilu Abuja ni wọn ti gbe idajọ naa kalẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee,  adajọ Inyang Ekwo lo jokoo lori aga idajọ to da ẹjọ naa nu, o si kede pe ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ ni ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe ta ko gomina naa pẹlu bi wọn ṣe sọ pe iwe-ẹri ti Abdurazaq n ko kiri ko mọyan lori.

Ile-ẹjọ ni awọn olupẹjọ ko fi ẹri kankan gbe ẹsun wọn lẹsẹ, awawi ati agbọsọ ni ohun ti wọn ro lẹjọ tori pe Abdurazaq ko kopa nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ wọn, ati pe ọrọ ti ko kan ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn n da si, tori pe ki i ṣe inu ẹgbẹ oṣelu kan naa ni wọn jọ wa. Adajọ tẹsiwaju pe irufẹ ẹjọ bayii, ẹni ti wọn jọ dije nibi idibo abẹle ẹgbẹ kan naa lo le pe e pe bọya o lo ayederu iwe-ẹri tabi pe o parọ fun ẹgbẹ. Fun idi eyi, ẹjọ ti PDP pe ko lẹsẹ nilẹ.

 

Leave a Reply