Faith Adebọla
Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDD, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ pe orileede Naijiria ni yoo jẹ orileede ilẹ Afrika kẹta ti ile-ẹjọ giga ju lọ yoo ti wọgi le eto idibo sipo aarẹ ti ko kunju oṣuwọn, o loun nigbagbọ ati igbẹkẹlẹ pe Supirimu kọọtu ilẹ wa ko ni i ṣe ohun to yatọ si eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji to lọ yii, o ni wọn maa da eto idibo naa nu bii omi iṣanwọ ni.
Atiku sọrọ yii laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji yii, latẹnu agbẹnusọ fun eto ipolongo ibo aarẹ rẹ, Amofin Daniel Bwala.
Atiku ni kawọn eeyan to n lero pe ikede ti ajọ eleto idibo (INEC), ba ti ṣe lori idibo aarẹ labẹ ge, ki wọn yaa tun inu wọn ro, ki wọn si simẹdọ, tori ko sohun toju o ri ri, bo ba ti ṣẹlẹ nibi kan, o le ṣẹlẹ nibibikibi.
Lori ikanni agbọrọkaye tuita rẹ ni wọn ti fi ọrọ naa lede, o kọ ọ sibẹ pe:
“Nigba ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede Kenya, nilẹ Afrika wa nibi wọgi le eto idibo sipo aarẹ orileede naa fun igba akọkọ nilẹ adulawọ, ohun tawọn eeyan sọ ni pe ọjọ manigbagbe leyi fawọn eeyan ilẹ Kenya, ati fun gbogbo olugbe kọntinẹẹti Afrika lapapọ.
“Fun igba akọkọ ninu itan oṣelu ati iṣejọba dẹmokiresi nilẹ Afrika, ile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ lati wọgi le eto idibo ti ko mọyan lori, wọn palẹ eto idibo rakuraku mọ. Idajọ to laami-laaka yii si fihan pe ijọba dẹmokiresi ti tubọ rẹsẹ walẹ nilẹ Afrika.
“Lẹyin ti Kenya, ile-ẹjọ giga ju lọ lorileede Burundi ti ko jinna si wa nibi naa ti ṣe bii tiwọn, wọn wọgi le eto idibo ti ko kunju oṣuwọn, nibẹ.
“Ẹ lọọ kọ ọrọ mi yii silẹ o, Naijiria ni yoo ṣikẹta tiru ẹ ti maa waye, ẹẹ sọ pe mọ wi bẹẹ.”
Amọ ṣa o, oriṣiiriṣii oju lawọn to kọ ọrọ sabẹ ohun ti Atiku sọ yii fi wo ọrọ to sọ naa. Ọpọ awọn to fesi sọrọ yii ni wọn sọ pe inu awọn iba dun-dun-un-dun biru idajọ ododo bẹẹ ba waye, amọ awọn o nigbẹkẹle ninu ile-ẹjọ giga ju lọ ti Naijiria, wọn ni bii igba teeyan n fẹjọ ika sun ika lọrọ wọn, to ba ti dọrọ idibo, wọn lawọn o reti pe iru idajọ to muna bẹẹ le waye.
Awọn mi-in ni ala ọsan-gangan ni Atiku n la, tori bile-ẹjọ ba tiẹ da ibo naa nu, ti wọn si tun un di, ba a ba ju abẹbẹ soke nigba igba, ibi pẹlẹbẹ ni yoo fi lelẹ, wọn ni Tinubu, iyẹn Aṣiwaju Bọla Ahmed, ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, ti wọn ti kede p’oun lo jawe olubori naa ni yoo tun jawe olubori, wọn ibaa tun ibo ọhun di nigba mẹwaa.
Bẹẹ si lawọn mi-in n sọ pe ati Atiku, ati Tinubu o, Peter Obi, ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party, lo yege ibo, wọn loun ni Ifa yoo fọre fun nile-ẹjọ nigbẹyin, afi bi idajọ naa ko ba lọ bo ṣe yẹ ko lọ.