Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ti dajọ pe Senetọ Ademọla Adeleke ni ojulowo oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo gomina to waye nipinlẹ Ọṣun loṣu Keje, ọdun yii.
Awọn adajọ yii fagi le ẹjọ ti Ọmọọba Dọtun Babayẹmi pe ta ko Adeleke, wọn si sọ pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.
A oo ranti pe awọn igun to fara mọ Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ninu ẹgbẹ PDP ṣe idibo pamari tiwọn ni WOCDIF Centre, Oṣogbo, nigba ti awọn igun ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke ṣe tiwọn ni papa iṣere ilu Oṣogbo, awọn alakooṣo ẹgbẹ wọn ati ajọ INEC si wa nibẹ.
Lẹyin idibo abẹle yii, Ọmọọba Babayẹmi fori le ile-ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Oṣogbo lati pe jijẹ ọmọ-oye Adeleke nija, o ni ki kootu kede oun gẹgẹ bii ojulowo oludije fun ẹgbẹ naa.
Ninu idajọ ọjọ naa, ile-ẹjọ sọ pe loootọ ni Babayẹmi ni awọn aṣoju ti wọn jẹ ojulowo gẹgẹ bii idajọ ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ọṣun ṣe wi ṣaaju, ṣugbọn wọn ko ṣeto idibo naa nibi to bofin mu, nitori naa, ko ni ẹtọ lati pe idibo naa nija.
Babayẹmi tun mori le ile-ẹjọ kotẹmilọrun lati yi idajọ ile-ẹjọ giga ijọba apapọ yii danu, ṣugbọn pabo lo tun ja si.
Idi niyi ti Babayẹmi fi lọ sile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii. Ninu idajọ naa to waye lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, Onidaajọ Amina Augie to dari awọn adajọ naa sọ pe agbẹjọro Babayẹmi gbe ẹjọ naa wa lẹyin asiko ọjọ mẹrinla ti ofin la silẹ fun un lati pe ẹjọ naa.