Jọkẹ Amọrin
Ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Supreme Court, ti fi idajọ lori boya ki a maa na owo Naira ati tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe si ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Lasiko igbẹjọ naa to waye niluu Abuja, ti awọn igbimọ ẹlẹni mẹsan-an jokoo lati gbọ, eyi ti John Okoro dari wọn, fẹnu ko pe ki wọn sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, iyẹn lẹyin ti awọn agbẹjọrọ igun mejeeji ti wi awijare wọn.
A o maa fi iroyin naa to yin leti bo ba ṣe n lọ