Ile-ẹjọ yẹ aga nidii MC Oluọmọ, wọn wọgi le igbimọ alakooso gareeji to n dari

Faith Adebọla, Eko

Ile-ẹjọ giga to n ri si ọrọ awọn ileeṣẹ ati ẹgbẹ nilẹ wa, National Industrial Court of Nigeria, NICN, eyi to fikalẹ siluu Eko, ti paṣẹ pe bijọba ipinlẹ Eko ṣe fofin de ẹgbẹ awọn onimọto nipinlẹ Eko, ti wọn si yan igbimọ ti yoo maa ṣakoso awọn gareeji rọpo ẹ, eyi ti wọn fi alaga ẹgbẹ awọn onimọto tẹlẹri, Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, jẹ adari igbimọ ọhun ko bofin mu rara, ko si tọna. Wọn ni kijọba Eko ko gbogbo igbimọ gareeji wọn ọhun kuro nilẹ lẹyẹ-o-sọka, ki ẹgbẹ onimọto, Road Transport Employers Association of Nigeria (RTEAN), pada sawọn ibudokọ ati gareeji gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe tẹlẹ.

Ẹgbẹ awọn onimọto kan ti wọn saaba maa n pe ni Roodu lo wọ ijọba ipinlẹ Eko lọ si kootu ninu ẹjọ kan ti wọn pe loṣu Kẹwaa, ọdun 2022. Nọmba iwe ipẹjọ ọhun ni NICN/LA/381/2022.

Ẹgbẹ naa rọ ile-ẹjọ lati wo aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Eko pa loṣu Kẹwaa, ọdun 2022, pe awọn ti tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ onimọto RTEAN awọn ka, awọn o si fẹẹ gbọ ohun to n jẹ Roodu tabi Naṣanna lawọn ibudokọ ati gareeji kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Eko mọ.

Ijọba lawọn ti gbe igbimọ tuntun kan kalẹ, eyi ti yoo maa ṣakoso awọn gareeji kaakiri, ti yoo si maa ja tikẹẹti fawọn onimọto lojoojumọ, ti yoo si maa ṣoju funjọba Eko lawọn ibudokọ ero gbogbo. Igbimọ ọhun, ti wọn pe ni Lagos State Parks and Garrages Administrators, ni wọn fi MC Oluọmọ ṣe alaga rẹ.

Ninu ẹjọ ọhun, gomina ipinlẹ Eko ni olujẹjọ akọkọ, Kọmiṣanna feto idajọ l’Ekoo, Moyọsọrẹ Onigbanjo, ni olujẹjọ keji, nigba ti Ọgbẹni Ṣọla Giwa, ti i ṣe oludamọran pataki si gomina lori eto irinna, jẹ olujẹjọ kẹta. Awọn mẹrinlelọgbọn mi-in ti wọn tun pe lẹjọ ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, ati gbogbo ọmọ igbimọ Parks and Garrages ti MC Oluọmọ ṣalaga wọn.

Lasiko ti igbẹjọ waye ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, agbẹjọro fun olupẹjọ, Amofin agba Elisah Kurah, ṣalaye pe ofin to ṣedasilẹ ẹgbẹ onimọto fun ẹgbẹ naa laṣẹ ati ominira igbokegbodo wọn, o ni ‘kan’mi o si ninu oku Iya Adele’ lọrọ ẹgbẹ naa jẹ funjọba, ijọba o si laṣẹ lati ṣofin kan-n-pa kan lori wọn, tabi ki wọn lawọn tu igbimọ wọn ka, tabi fofin de wọn, bii iru eyi tijọba Eko lawọn ṣe yii, tori ẹgbẹ naa forukọ silẹ labẹ ofin Trade Union Act tọdun 2004.

O ni ijọba apapọ, labẹ ẹka ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ati igbani-siṣẹ, iyẹn Federal Ministry of Labour and Employment, lo le da sọrọ ẹgbẹ onimọto, ki i ṣe ijọba Eko.

Amọ agbejọro fun ijọba Eko, Amofin agba Adebayọ Haroun ni ko sohun to buru ninu igbesẹ tijọba gbe lori ẹgbẹ onimọto ọhun, ati bi wọn ṣe fofin de igbokegbodo wọn nipinlẹ Eko, tori ojuṣe ijọba ni lati pese aabo, ki wọn si pa alaafia ilu mọ, bi ẹgbẹ onimọto ba si fẹẹ maa dana ijangbọn silẹ, ti awọn ẹgbẹ onimọto roodu n ṣakọlu si Nasanna, ti wọn si ti n da omi alaafia ilu ru kaakiri, ijọba o le fọwọ lẹran siru nnkan bẹẹ, eyi lo fa igbesẹ ijọba lori wọn.

Bakan naa ni Amofin agba Taiwo Kupọlati, to jẹ lọọya MC Oluọmọ atawọn ọmọ igbimọ mẹtalelọgbọn rẹ kin lọọya ijọba Eko lẹyin, o ni ojuṣe gomina ipinlẹ Eko ni lati pese aabo, ki alaafia  si jọba nipinlẹ rẹ, tori eyi, ko si aburu kan ninu igbesẹ ijọba.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Abilekọ Maureen Ẹsowẹ ni oun ti gbọn gbogbo iwe ofin ati alakalẹ ijọba to rọ mọ idasilẹ awọn ẹgbẹ onimọto yii yẹbẹyẹbẹ, oun si wo o finni-finni, oun ko ri ibi ti ijọba ti laṣẹ lati fofin de wọn, tabi yan igbimọ kan rọpo wọn. O ni igbesẹ ijọba yii ko bofin mu pẹẹ, tori ẹ, ki wọn jawọ ninu aapọn ti o yọ.

O ni ohun to yẹ ki okobo ijọba Eko bọ, wọn o bọ ọ, ti wọn fi n lawọn le bọ igba abẹrẹ ninu ookun. O ni bi ẹgbẹ onimọto ba n ba ara wọn ja, ojuṣe ijọba ati awọn ọlọpaa ni lati fi pampẹ ofin gbe awọn to ba lọwọ ninu ija naa, ki wọn si ba wọn ṣẹjọ ni kootu lẹyin iwadii to muna doko, tabi ki wọn mọ ohun to ṣokunfa ija, ki wọn si ṣeto alaafia laarin tọtun-tosi nitubi inubi.

Adajọ naa kilọ pe kijọba yee da si ọrọ abẹlẹ awọn ẹgbẹ onimọto, tori iru aṣa bẹẹ lodi sofin. Bakan naa lo tun kilọ fun ijọba, awọn ọlọpaa, tabi awọn agbofinro gbogbo, lati ma ṣe dunkooko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto atawọn oṣiṣẹ wọn, wọn o si gbọdọ gbegi dina fun wọn lati wọ ọfiisi wọn, tabi ṣiṣẹ wọn lawọn gareeji gbogbo.
Gbogbo aroye ati atotonu olujẹjọ kin-in-ni titi dori olujẹjọ kẹtadinlogoji, ni Adajọ Esowẹ rọ danu, o ni awawi ati airikan-sọ ni gbogbo ẹ, ko tẹwọn loju ofin, oun ko fara mọ ọn.

O ni ki wọn lọọ mu aṣẹ ile-ẹjọ naa ṣẹ ni waranṣeṣa ni o.

Leave a Reply