Ile-ẹjọ yọ igbakeji olori aṣofin Ondo nipo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ giga kan to filu Akurẹ ṣe ibujokoo, ti yọ Ọnarebu Samuel Aderọboye nipo gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo.

Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Adetan Osadebey, ninu idajọ to gbe kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, paṣẹ yiyọ Ọnarebu to n ṣoju ẹkun idibo keji Odigbo ọhun bii ẹni yọ jiga, ki wọn si da Ọnarebu Irọju Ogundeji pada saaye rẹ lẹyẹ-o-sọka.

Ọdun 2020 lawọn aṣofin ile-igbimọ ọhun kan ko ara wọn jọ, ti wọn si lawọn ti dibo lati yẹ aga mọ Ọnarebu Irọju to n ṣoju awọn eeyan Odigbo ẹkun kin-in-ni nidii gẹgẹ bii igbakeji olori awọn aṣofin latari ede aiyede nla kan to waye laarin oun ati olori ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun lori ọrọ yiyọ igbakeji gomina igba naa, Agboọla Ajayi nipo.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ri ẹsun kan to ṣe koko fi kan Irọju nigba naa, ohun ti wọn n pariwo pe awọn awọn tori rẹ yọ ọ nipo ni titapa si ofin ati ilana ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo.

Loju-ẹsẹ ni wọn si ti dibo yan Ọnarebu Aderọboye ti wọn jọ wa lati ijọba ibilẹ kan naa, ṣugbọn ti wọn n ṣoju ẹkun ọtọọtọ lati fi rọpo rẹ.

Eyi lo bi ọkunrin naa ninu to fi gba ile-ẹjọ lọ nipasẹ agbẹjọro rẹ, Amofin agba Wale Ọmọtọṣọ, o ni ọna ti wọn fi yọ oun nipo ko ba ofin orilẹ-ede yii mu, nitori wọn kuna lati tẹle abala ofin kẹsan-an, ila kin-in-ni, de eẹkẹwaa, eyi to fi dandan le e pe awọn ti yoo yọ ẹyikeyii ninu awọn oloye ile-aṣofin nipo gbọdọ ko ida meji ninu mẹta awọn ọmọ-ile.

Kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Charles Titiloye lo waa gbẹnusọ fun ile-igbimọ aṣofin naa, ohun ti oun si duro le lori ni pe, awọn to yọ Ọnarebu Irọju nipo ko ṣe ohun to ta ko ofin rara.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Osadebey ni iwadii ile-ẹjọ naa fidi rẹ mulẹ pe loootọ l’awọn aṣofin ọhun kọ lati tẹle ilana ofin ninu igbesẹ wọn lati yẹ aga mọ igbakeji abẹnugan naa nidii nitori ko sibi ti wọn ti fun niwee waa wi tẹnu rẹ ki wọn too yọ ọ.

Adajọ ni ko si ṣiṣe tabi aiṣe, afi ki wọn da Irọju pada sipo rẹ kiakia ki Aderọboye si yee pe ara rẹ ni igbakeji abẹnugan ile lati akoko naa lọ.

Ile-ẹjọ tun ni ile-aṣofin ọhun tun gbọdọ san gbogbo owo-oṣu ati awọn ajẹmọnu rẹ lati ọjọ ti wọn ti yọ ọ nipo fun un patapata, yatọ si mliọnu mẹwaa Niara to ni ki wọn san fun un gẹgẹ bíi owo gba, ma binu, fun iya ti wọn fi jẹ ẹ lọna aitọ.

Leave a Reply