Ile-ẹjọ yọ oludije APC danu ni Kwara

Ibrahim Alagunmu Ilọrin

Ile-ẹjọ giga kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti da ibo to gbe ọmọọleegbimọ aṣoju-ṣofin kan Raheem Ọlawuyi Ajulọ-Opin, nu gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ APC, lẹkun idibo Isin/Oke-Ẹrọ/Ekiti, ni Guusu Kwara. O fi ontẹ jan Oluṣẹgun Adebayọ gẹgẹ bii ojulowo oludije nibi idibo ọdun 2023.

Ajulo-Opin, ni wọn dibo yan gẹgẹ bii aṣofin nibi atundi ibo to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2018, ti o si tun n tẹsiwaju ipo rẹ nibi eto idibo apapọ ọdun 2019.

Ajulo-Opin kopa ninu eto idibo abẹle to gbe Sẹnetọ Lọla Ashiru wọle gẹgẹ bii oludije dupo sẹnetọ lẹkun idibo Guusu Kwara, ninu ẹgbẹ oselu APC, nibi eto idibo ọdun 2023, to si padanu sọwọ Lọla Ashiru.

Adebayọ ni tiẹ kopa ninu eto idibo abẹle APC fun ileegbimọ aṣoju-ṣofin, o si jawe olubori, eyi to mu ki wọn kede rẹ gẹgẹ bii oludije dupo ẹgbẹ naa fun ẹkun idibo Isin/Oke-Ero/Ekiti/Irẹpọdun. Ṣugbọn ẹgbẹ tun idibo mi-in ṣe, wọn si kede Ajulọ-Opin gẹgẹ bii oludije to jawe olubori.

Igbesẹ naa ni ko tẹ Adebayọ lọrun lo fi gba ile-ẹjọ lọ. L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni kootu fidi rẹ mulẹ pe Adebayọ ni ojulowo oludije, to si yọ Ajulọ-Opin kuro gẹgẹ bii oludije nibi eto idibo ọdun 2023.

Leave a Reply