Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Irinṣẹ itọju alaisan to din diẹ ni miliọnu lọna igba naira (194m) ni ilẹ Olomirina Czech fi ta ipinlẹ Ogun lọrẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu karun-un yii, wọn ni ki itọju le rọrun si i ni.
Awọn nnkan eelo itọju naa ni: Bẹẹdi yara itọju awọn aisan to lagbara gan-an (ICU) mẹẹẹdogun, maṣinni ti wọn maa n gbe awọn ọmọ ti oṣu wọn ko pe si (Incubator), ẹyọ kan, awọn ibusun ọmọde, ẹrọ amunawa (jẹnẹretọ) ati ẹrọ kan ti wọn fi n tan ina sawọn ọmọ to ba ni aisan ‘Jaundice’(Iba pọnju) lara (Phototherapy machine).
Nigba to n ko awọn nnkan eelo yii kalẹ lọfiisi Gomina Dapọ Abiọdun, l’Abẹokuta, Aṣoju Ilẹ Olominira Czech ni Naijiria, Ọgbẹni Marek Skolil, sọ pe nnkan idunnu lo jẹ fun orilẹ-ede awọn lati ran ipinlẹ Ogun lọwọ labala ilera.
O ni bi Naijiria to jẹ ilu nla nilẹ Adulawọ ko ṣe ni idagbasoke ko tẹ ijọba awọn lọrun, to jẹ titi de ibi ilera ni iṣoro ti wa fun wọn.
Ninu ọrọ Gomina Dapọ Abiọdun, o ni inu oun dun pupọ pe asiko ti ipinlẹ Ogun ati Naijiria lapapọ nilo iranlọwọ awọn eeyan yii ni wọn waa ṣe e. Gomina dupẹ lọwọ ilẹ Czech, o si rọ wọn pe ki wọn ma dawọ iranlọwọ yii duro, ki wọn tun jẹ ko de ẹka imọ ẹrọ ati afẹfẹ.
Gomina loun mọ pe ilẹ Czech nimọ pupọ lẹka imọ ẹrọ, iṣẹ ọgbin atawọn nnkan amayedẹrun. O ni awọn ẹka toun gẹgẹ bii gomina nigbagbọ pe awọn le jọ ṣiṣẹ pọ ni.
O fi kun un pe ọkọ agbokuu-gbe-alaisan (Ambulance) bii mẹfa loun n reti lati gba ki ọsẹ yii too pari, o ni kawọn Czech ma gbagbe ileri wọn lati fun ipinlẹ Ogun lawọn ọkọ yii.
Bakan naa ni kọmiṣanna fun eto ilera nipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker, dupẹ lọwọ awọn to ṣe ipinlẹ Ogun loore yii. O ni Ijẹbu-Ifẹ, ọkan ninu awọn ilu ti aṣoju Czech ṣabẹwo si, ni awọn nnkan eelo naa yoo wa.