Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisreeti kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti dajọ ẹwọn ọdun kan aabọ fun ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Joe Barnabas, lori ẹsun jija awọn ọga rẹ lole.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni olujẹjọ ọhun kọkọ fara han nile-ẹjọ, ọjọ naa gan-an ladajọ si fori ẹjọ rẹ ti sibi kan, niwọn igba toun funra rẹ ti gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Ni ibamu pẹlu ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ lasiko igbẹjọ, olujẹjọ ọhun ni wọn lo ji foonu olowo nla mẹta, ọpa aṣọ Kampala marun-un ati towẹli kan ti apapọ owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le ẹẹdẹgbẹrin Naira (#300, 700). Awọn ẹru wọnyi ni wọn lo jẹ ti Adejuwọn Verona.
Barnabas ni wọn ko duro lori eyi nikan, ṣe awọn agba bọ, wọn ni aji ede jẹ ko ni i jẹ ẹyọ kan ko ṣiwọ, ile ẹlomi-in ti wọn porukọ rẹ ni Orisadare Ọlayẹmi lo tun gba lọ, nibi to ti ji ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, bata olowo nla kan ati awọtẹlẹ ọkunrin mẹta.
Apapọ owo awọn nnkan to ji lẹẹkeji ni wọn lo to bii ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹfa Naira din ẹyọ kan (#109, 000).
Ẹni kẹta wọn, Adamọlẹkun Oludare, naa ko sai fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun pẹlu bo ṣe tun kọja si yara tirẹ, nibi to ti ji sẹẹti kan ti ko ju ẹgbẹrun mẹrin aabọ pere lọ.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye lagbegbe Alagbaka, lọjọ kẹta, ninu oṣu kẹwaa, ọdun 2021.
Gbogbo awọn ẹsun yii ni ọlọpaa agbefọba, Akintimẹhin Nelson ni o tako abala irinwo din mẹwaaa (399) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Akintimẹhin ni inu oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni Barnabas de siluu Akurẹ, to si bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii ọlọdẹ ninu ọgba ile tawọn mẹtẹẹta to ja lole n gbe ninu oṣu kẹsan-an.
O ni ki i ṣe ẹẹkan ṣoṣo lo ji awọn ẹru naa, diẹdiẹ lo n ji wọn titi ti aṣiri rẹ fi tu.
Akintimẹhin ni ọdaran ọhun ti kọkọ ṣe ẹda awọn kọkọrọ to wọ ile ọkọọkan awọn olugbe ile naa, lẹyin to ba si ti silẹkun abawọle tan ni yoo too gba oju fereṣe ile-idana wọ yara ẹnikọọkan.
O ni nigba tawọn olugbe ile ọhun ṣakiyesi pe nnkan awọn n sọnu ni wọn lọ sagọọ ọlọpaa lati fẹjọ sun.
Gbogbo ẹru ti wọn n wa naa ni wọn pada ri ninu yara Barnabas, toun funra rẹ si jẹwọ pe loootọ loun ji wọn ko.
Agbefọba ni oun ti ṣetan fun igbẹjọ, niwọn igba ti mẹrin ninu awọn ẹlẹrii marun-un ti oun ni ti wa ni kootu.
Nigba ti wọn beere lọwọ olujẹjọ ọhun boya o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi, o kọkọ ni oun ko jẹbi, ṣugbọn nigba ti adajọ bi i leere bi awọn ẹru ti wọn ba ni ikawọ rẹ ṣe jẹ, o ni oun loun ji wọn ko ninu ile awọn ọga oun ti wọn gba oun lati maa ṣọ.
O ni ọna ti akọwe kootu fi beere lọwọ oun ni ko ye oun daadaa ti oun fi kọkọ sọ pe oun ko jẹbi.
Barnabas ni oun mọ pe oun jẹbi, ati pe kile-ẹjọ ba oun bẹ awọn ọga oun ti oun ja lole. Ó ni oun ko tun jẹ dan iru rẹ wo mọ bi wọn ba le foriji oun.
Onidaajọ Musa Al-Yinus ni awọn olupẹjọ ti fidi ẹri wọn mulẹ kọja iyemeji. O ni ki Barnabas tete lọọ fẹwọn ọdun kan jura lori ẹsun kin-in-ni pẹlu ẹwọn oṣu mẹfa lori ẹsun keji.
Apapọ ọjọ ti yoo lo lẹwọn waa jẹ ọdun kan aabọ gbako.