Jọkẹ Amọri
Owe Yoruba kan lo sọ pe nibi ti erin meji ba ti ja, koriko ibẹ lo maa fara gba a. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu ija ajaku akata ti ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo nilẹ wa, NNPC ati ẹgbẹ awọn alagbata epo n ba ileeṣẹ Dangote ja lori ileeṣẹ ifọpo ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ bayii. Nibi ti ọrọ si de duro, afi kijọba apapọ tete wa nnkan ṣe si wahala tawọn NNPC n ba ileefọpo Dangote fa, ki awọn araalu ma baa maa jiya lori ohun alumọọni ti Ọlọrun fi fun wọn.
Ni bayii, ọga agba patapata fun eto iroyin nileeṣẹ Dangote, Ọgbẹni Anthony Chiejina, ti sọ pe irọ nla to jinna soootọ ni ohun ti ẹgbẹ awọn alagbata epo bẹntiroolu nilẹ wa, Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria (IPMAN) ati ẹgbẹ awọn to n ta epo fun awọn ileepo kaakiri ilẹ wa, Petroleum Product Retails Outlets Owners Association of Nigeria (PETROAN) n sọ pe iye ti awọn n gbe epo lati ilẹ okeere dinwo ju iye ti Dangote n ta tiẹ lọ.
Egbẹ awọn alagbata epo ta a mọ si (IPMAN), ni wọn maa n gba epo tiwọn taara lati ileefọpo, ti wọn si n ta a fun awọn alaarobọ, iyẹn (PETROAN), awọn alarobọ yii lo n pin epo naa kaakiri fun awọn ileepo lọlọkan-o-jọkan. Anthony sọ pe awọn ẹgbẹ naa ko sọ tootọ lori iye ti Dangote n ta epo rẹ, o ni irọ ni wọn n pa fun araalu.
Ninu alaye to ṣe ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, Sunday, ọjọ kẹta, oṣu yii, lo ti sọ pe, ‘’A n yẹra lọpọ igba lati maa pẹlu ọbọ jawura pẹlu awọn ẹgbẹ yii, a o si fẹẹ maa jagun ọrọ pẹlu wọn, ṣugbọn eyi ko sọ pe ka ma le fesi si irọ ojukoroju ti wọn n pa lori iye ti a n ta epo wa.
‘’Ẹgbẹ mejeeji sọ pe awọn n gba epo to din si iye ti a n ta tiwa lati ilẹ okeere. Awa gbe ote iye epo wa le oṣunwọn iye ti wọn n ta a lọja agbaye, tiwa si rọju si iye ti awọn to n lọọ gbe e wa lati Oke-Okun kaakiri n ta a lọ.
‘’Ni ti epo NNPC, ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrun o din mẹsan-an (971) ni NNPC n ta a fawọn to n fi ọkọ oju omi ra a, nigba ti wọn n ta a fun awọn oni tirela ni ẹgbẹrun kan o din mẹwaa (990)
Ṣugbọn ki nnkan le lọ daadaa, ati fun irọrun awọn ọmọ Naijiria, ọtalelẹẹẹdẹgbẹrun (960) lawa n ta epo tiwa fun awọn ọkọ oju omi to n gbe e kaakiri, nigba ti a n ta a fun awọn ọkọ elepo ni ẹgbẹrun kan din mẹwaa (990).
Bẹ o ba gbagbe, ija abẹlẹ ti n lọ laarin ileeṣẹ ifọpo Dangote ati ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, (NNPC), pẹlu bi wọn ṣe kọ lati maa gba epo lọwọ Dangote pẹlu awawi loriṣiiriṣii.
Awawi ti wọn kọkọ n ṣe ni pe ileeṣẹ ifọpo Dangote ko le pese iye epo ti Naijiria yoo maa lo, ṣugbọn loju-ẹsẹ ni ileeṣẹ Dangote ti jade, ti wọn ni Naijiria ko le lo epo ti awọn ba fọ lojumọ kan tan, nitori bii miliọnu lọna ẹgbẹrun lita lawọn n ṣe lojumọ, bẹẹ ni awọn tun ṣe miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta bẹntiroolu pamọ, nitori idagiri.
Bakan naa ni ileeṣẹ ifọpo Dangote tun dahun si ahesọ tawọn eeyan naa tun sọ pe owo epo Dangote wọn ju eyi ti awọn n gba nilẹ okeere lọ.
Ohun ti ọpọ awọn eeyan n beere ni pe ọgbọn wo lo wa ninu ki NNPC ma mu owo ile lọ sita, ki wọn si tun maa dẹ awọn eeyan lati ba orukọ ileeṣe ifọpo Dangote to jẹ tiwa-n-tiwa jẹ.