Adewale Adeoye
Awọn agba bọ wọn ni ko si awijare kankan fẹni to faṣọ ọlọpaa gba paarọ. Bẹẹ gan-an lo ri fun oyinbo alawọ funfun kan to jẹ ọmọ orileede China, to yẹpẹrẹ owo Naira ilẹ wa nita gbangba.
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣeleri pe awọn maa ba a na an tan bii owo ni, wọn lawọn maa wọ ọ lọ sile-ẹjọ lori ẹsun yii.
ALAROYE gbọ pe ṣe ni oyinbo naa ta a ko mọ orukọ rẹ lasiko ta a n ko iroyin yii jọ fibinu ya owo Naira ilẹ wa pẹrẹpẹrẹ nita gbangba, niṣoju awọn agbofinro kan ti wọn lọọ ti ileeṣẹ rẹ to wa lojuna marosẹ Lekki si Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, pa laipẹ yii.
Ibinu pe awọn agbofinro naa waa tileeṣẹ rẹ pa lo mu un ko ya owo Naira nita gbangba. Bo ṣe n ya owo naa, bẹẹ lo n ṣepe nla-nla fawọn agbofinro ti wọn wa nibẹ pẹlu ede abinibi rẹ.
Ṣa o, Alukoro agba funleeṣe ọlọpaa orileede yii, A.C.P Olumuyiwa Adejọbi, ti ke si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, pe ko ṣewadii daadaa nipa iṣẹlẹ ọhun, ko si gbe igbesẹ gidi lori ọrọ naa ni kia.