Faith Adebọla, Eko
Ọpẹlọpẹ awọn lọgaa-lọgaa ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti wọn tete gbọ siṣẹlẹ ọhun, ti wọn si duro lori idajọ ododo, miliọnu mẹẹẹdogun lawọn agbofinro kan ti Ọgbẹni Ṣẹgun ko sakolo wọn kọkọ lawọn maa gba ki wọn too gba ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ ẹ.
Ọdọbinrin Rinu Oduala, ọkan lara awọn to ṣagbatẹru iwọde ta ko SARS to kọja, lo kọ ọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun sori atẹ ayelujara, lori ikanni abẹyẹfo ẹ (twitter) pe lati ilu Dubai, ni orileede UAE (United Arab Emirates), ni ọrẹ oun Ṣẹgun ti n bọ, bo si ṣe n kuro ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed, ni Ikẹja, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee yii, o pe taksi Uber kan lati waa gbe oun lọ si agbegbe Festac, nipinlẹ Eko.
Bi wọn ṣe n lọ lọna, o ku diẹ ki wọn de Festac lawọn ọlọpaa kan da ọkọ ayọkẹlẹ wọn duro, lẹyin ti wọn ṣayewo iwe ọkọ, wọn wo buutu mọto ọhun, wọn si ri baagi ti Ṣẹgun ko awọn aṣọ ati dukia ẹ si, eyi lo jẹ ki wọn tete mọ pe ṣẹṣẹde to n bọ latilu oyinbo ni.
Kia ni wọn ti yi ọrọ pada, wọn paṣẹ fonimọto naa lati tẹle awọn de teṣan wọn ni Festac, wọn yọ foonu to wa ninu baagi ẹ, wọn si bẹrẹ si i halẹ mọ-ọn loriṣiiriṣii.
Asẹyinwa asẹyinbọ, wọn lawọn maa gba miliọnu mẹẹẹdogun naira (N15m) lọwọ Ṣẹgun kawọn too fi i silẹ, aijẹ bẹẹ, awọn yoo ti i mọle, ohunkohun lo si le ṣẹlẹ si i.
Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ, wọn mu ọkunrin naa lọ sibi ti ẹrọ POS kan wa nitosi teṣan naa, ni wọn ba gba ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000) lọwọ ẹ, wọn fa owo naa yọ ninu akanti ẹ ni, wọn o si sọ pe Ṣẹgun ṣẹ wọn lẹṣẹ kan ju pe o ṣẹṣẹ n ti ilu oyinbo bọ lọ.
Ṣẹgun lo sọrọ yii fun ọrẹ ẹ, Rinu, lọrọ ọhun ba di ohun tawọn eeyan n gba bii ẹni gba igba ọti lori atẹ ayelujara, ti wọn si bẹrẹ si i naka abuku sileeṣẹ ọlọpaa.
Ọrọ ọhun ja ranyin titi de ọdọ awọn lọgaa lọgaa ileeṣẹ ọlọpaa. Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro wọn l’Ekoo ni bi Kọmiṣanna wọn, Hakeem Odumosu, ṣe gbọ nipa ẹ lo ti ni ki wọn bẹrẹ iwadii, wọn si fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn ọlọpaa kan huwakiwa ọhun, ki i ṣe pe wọn purọ mọ wọn.
Adejọbi ni wọn ti ke si Ṣẹgun, o si ti wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa lowurọ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ibẹ ni wọn ti ko ẹgbẹrun lọna igba naira owo aitọ tawọn agbofinro naa gba lọwọ ẹ pada fun un, tọkunrin naa si dupẹ lọwọ wọn.
Adejọbi ni iwadii ti foju awọn alainitiju agbofinro to lọwọ ninu iwa ọbayejẹ naa han, awọn si ti faṣẹ ofin mu wọn lati tubọ ṣewadii nilana ileeṣẹ ọlọpaa.
O ni kọmiṣanna ọlọpaa Eko ti ni kawọn araalu lọọ fọkan balẹ, awọn maa da sẹria to tọ fẹnikẹni ti ajere iwa ibajẹ bii eyi ba ṣi mọ lori, tori ofin o moju ẹnikẹni.