Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu pasitọ to gbe ibọn wọnu ṣọọṣi lasiko to n waasu

Monisọla Saka

Lọdọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ to n wadii iwa ọdaran labẹlẹ, iyẹn Force Intelligence Bureau, to wa niluu Abuja, ni Pasitọ kan torukọ rẹ n jẹ Uche Aigbe, ti ijọ House on the Rock, ẹka ti iluu Abuja wa bayii to ti n sọ ohun to ri to fi gbe ibọn nla AK-47, lọ si ṣọọṣi rẹ lasiko ti isin n lọ lọwọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Keji yii.

Ki i ṣe oun nikan ni wọn mu o, wọn tun mu ọga ọlọpaa kan, Inspekitọ Musa Audu, fun bo ṣe gbe ibọn rẹ fun pasitọ yii lati lo. Ki i ṣe pe wọn mu un ti mọlẹ pẹlu pasitọ to gbebọn fun nikan, Kọmiṣanna ọlọpaa olu ilu ilẹ wa l’Abuja, Surdiq Abubakar ti mu amọran wa pe ki Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Usman Baba, gba aṣọ lọrun ọkunrin naa, ki wọn le e danu lẹnu iṣẹ agbofinro fun iwa to hu naa, iyẹn to ba wọ inu yara ti wọn ti n da sẹria fun awọn ọlọpaa ti wọn n pe ni orderly room tan, ti wọn si fiya to tọ jẹ ẹ.

Pasitọ Uche Aigbe, ti i ṣe ojiṣẹ Ọlọrun agba fun ile ijọsin House on the Rock, niluu Abuja, lo da ibẹrubojo ati jinnijinni silẹ ninu ijọ rẹ pẹlu lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun yii, pẹlu bo ṣe gbe ibọn wọ ṣọṣi, to si yan lọ si ori pẹpẹ pẹlu ibọn ọhun lejika rẹ bii ologun lasiko ti isin ẹlẹẹkeji, tawọn ero ti maa n pọ ju lọ n lọ lọwọ.

Niṣe lawọn ọmọ ijọ n woju ara wọn, ṣugbọn pasitọ yii ko tiẹ ṣe bii pe oun ri ẹnikẹni ninu awọn ọmọ ijọ rẹ ti ibẹru wa loju wọn ọhun.

Lasiko to fẹẹ ṣi bibeli rẹ lati maa ka a lo gboju soke lẹẹkan naa to sọ ọ pẹlu awada pe “Awọn eeyan kan n wa wahala mi. Emi naa si ti gbaradi, mo ti mura wọn silẹ”.

Nigba to n waasu pẹlu ori ọrọ to sọ pe ‘Pipa ọkan rẹ mọ kuro lọdọ awọn olukọ eke ati ‘igbagbọ lai si iṣẹ, oku ni‘’ Paitọ yii ni,

“Nilẹ toni to mọ, awọn pasitọ kan ni ẹbun irina, ṣugbọn to jẹ pe wọn n lọ kaakiri lati fi ẹbu yii lu awọn eeyan ni jibiti iṣẹ òógùn wọn ni. Idi niyi ta a fi gbọdọ gbe ‘ibọn’ wa, lati le daabo bo ara wa, ka si gbeja ara wa…

Ni kete ti fidio ojiṣẹ Ọlọrun ọhun de ori ẹrọ abẹyẹfo Twitter, lawọn ọmọ Naijiria ti ke si Olumuyiwa Adejọbi ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria lati waa wo nnkan tawọn ri, ko si sọrọ lori ohun ti pasitọ yii ṣe.

Lasiko to n fesi sọrọ naa, Adejọbi ni ibọn AK-47 to gbe dani yii wa lara awọn ohun ija ti ijọba orilẹ-ede Naijiria fofin de fun ẹnikẹni lati maa gbe kiri, awọn ẹṣọ alaabo ati ọmọ ogun ilẹ Naijiria nikan ni wọn lẹtọọ lati gbe e.

O loun ti gbe igbesẹ lori ọrọ naa, ohun si ti fi ohun ti pasitọ yii ṣe to kọmiṣanna ọlọpaa Abuja, ti i ṣe olu ilu orilẹ-ede yii leti.

Adejọbi ni, ‘‘To ba jẹ ootọ ni, a jẹ pe pasitọ ọhun ni ẹjọ lati jẹ lọdọ wa. AK-47 la pe e! Irufẹ ibọn to jẹ pe o wa lara awọn nnkan ija ti ijọba ṣe leewọ nilẹ yii ni, ki i ṣe gbogbo eeyan lo lẹtọọ lati maa gbe e kiri, ayafi awọn oṣiṣẹ eleto aabo kan atawọn ọmọ ogun ilẹ yii”.

Ṣugbọn ni bayii, pasitọ naa ti n sọ ohun to fa a to fi gbe ibọn wọnu ṣọọṣi fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ.

Leave a Reply