Ileeṣẹ oogun oloro skuchies lawọn eleyii da silẹ ni Sagamu

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti oogun oloro gbigbe ati ilokulo rẹ lorilẹ-ede yii, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ awọn afurasi kan, lasiko ti wọn ya bo ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe oogun oloro ti wọn n pe ni Skuchies, to wa lagbegbe Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.                     Gẹgẹ bi adari ajọ naa nipinlẹ Ogun, Ibiba Odili, ṣe sọ, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun yii, ni awọn oṣiṣẹ NDLEA mori le ileeṣẹ wọn to wa ni Ajaka, lagbegbe Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

Oogun lile to maa n ra eeyan niye, to si maa n jẹ keeyan ṣiwa-hu ni skuchies yii, oriṣiiriṣii egboogi oloro bio igbo, codeine, oogun ikọ olomi atawọn nnkan mi-in ni wọn da papọ ti wọn fi ṣe e.

Lara awọn nnkan ti wọn ri nibẹ ni igbo to to iwọn bii kilo mẹwaa, jálá ti wọn rọ oogun oloro skuchies yii si to  n lọ bii egbeje (1,356 liters), oogun oloro codeine bii ogún jálá, ẹrọ amomitutu meje, jẹnẹretọ nla, gaasi idana nla meji atawọn nnkan mi-in bẹẹ.

Bẹẹ ni wọn tun fidi ẹ mulẹ pe ọwọ awọn tẹ ọkunrin kan, Adekunle Adekọla, to jẹ ọkan lara awọn ti wọn n pese nnkan mimu to n pa ni lara yii. Ṣugbọn wọn ni obinrin kan ti wọn n pe ni Iya Tobi, ogbologboo oniṣowo skuchies, ti i ṣe olori awọn afurasi yii, toun funra ẹ si maa n ṣe oogun oloro buruku yii ta, ti fẹsẹ fẹ ẹ lasiko tawọn debẹ.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Odili fi sita lo ti ni, “Awọn ikọ to n tọpinpin nileeṣẹ ajọ NDLEA, ya wọ ileeṣẹ kan ti wọn ti n pese nnkan mimu skuchies, to wa lagbegbe Ajaka, Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, wọn si da gbogbo ẹ ru.

“Lara ẹru ofin ti wọn ba nibẹ, ti wọn si ti ko si akata wọn ni, ike oni lita marun-un skuchies lọna mẹrinlelọgọfa, igbo to gbe iwọn kilo mẹwaa, ogun lita oogun ikọ olomi to ni oogun oloro codeine ninu, ẹrọ amomitutu meje, gaasi idana nla meji, jẹnẹretọ ati ẹrọ gbohungbohun, stabilizer, ohun eelo idana igbalode (cooker), atawọn nnkan mi-in ti wọn n lo lati fi pese nnkan mimu yii.

‘’Lasiko ta a ya wọbẹ lọwọ wa tẹ afurasi kan torukọ ẹ n jẹ Adekunle Adekọla, ti ogbologboo oniṣowo skuchies yii, Iya Tobi, ti na papa bora”.

 

O ṣalaye siwaju si i pe gbogbo ẹru ofin tawọn ba nibẹ pata lawọn ti ko si akata awọn.

 

Leave a Reply