Stephen Ajagbe, Ilorin
Eeyan meje ọtọọtọ lori ko yọ ninu ijamba ti atẹgun ojo to rọ mọju ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja. Ileeṣẹ panapana tipinlẹ Kwara lo doola ẹmi wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nidojukọ ileejọsin C & S, lagbegbe Muritala, niluu Ilọrin.
Lara wọn ni awọn baba agbalagba ti atẹgun ojo naa wo orule ile lu mọlẹ, atawọn ọdọ pẹlu ọmọde.
Alukoro ileeṣẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, ṣalaye pe ileewosan gbogbogboo to wa lagbegbe Surulere, niluu Ilọrin, lawọn ko awọn eeyan naa lọ lati gba itọju.
Awọn ibomi-in ti wọn tun ti ri awọn eeyan doola ni Ita-Igba ati Emirs Road, laarin igboro ilu Ilọrin.
O ni iṣẹ ọhun ṣee ṣe pẹlu atilẹyin Kọmiṣanna fun iṣẹ ode ati irinna ọkọ, Alhaji Suleiman Iliasu, ẹni to kopa ribiribi lati ri i pe wọn ri awọn eeyan ọhun tọju nileewosan.
Ọga agba ileeṣẹ panapana, Alh. Waheed I. Yakub, gba araalu nimọran lati maa ṣọra, ki wọn si maa wa ibi to dara duro si lasiko ti atẹgun ojo ba n fẹ, ati bi ojo nla ba n rọ.