Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Okitipupa, ti dajọ ẹwọn ọdun meji fun awọn ọlọdẹ meji kan lẹyin tawọn funra wọn ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ole jija ti wọn fi kan wọn.
Awọn ọdaran mejeeji, Adebọla Ọmọmule ati Ese Sunday, ni wọn fẹsun kan pe wọn ja ileeṣẹ epo pupa kan to wa l’Ararọmi Obu, nijọba ibilẹ Odigbo, lole lọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun ta a wa yii.
Agbẹnusọ fun ijọba, Amofin O. F. Akeredolu, ni ṣe ni wọn gba Sunday ati ẹnikeji rẹ bii ọdẹ lati maa ba wọn sọ awọn nnkan ti wọn n peṣe nileeṣẹ ọhun.
Agbẹjọro naa ṣalaye pe odidi apo ẹyin mẹjọ, eyi ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (#150, 000) lawọn olujẹjọ naa ji ko nileeṣẹ ti wọn ni ki wọn maa ṣọ yii lalẹ ọjọ kan ṣoṣo.
Ẹsọ Amọtẹkun ni wọn ṣeto bọwọ ṣe pada tẹ awọn ọdaran mejeeji, ti wọn si ko wọn wa sile-ẹjọ lati waa foju wina ofin.
Awọn ọdaran ọhun ko fi asiko ile-ẹjọ ṣofo ti wọn fi gba pe awọn jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn ka si wọn lẹsẹ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Ṣekoni ni kawọn mejeeji lọọ fi odidi ọdun meji roko ọba ninu ọgba ẹwọn lai faaye owo itanran silẹ fun wọn.