Ileefọpo ilẹ wa ti NNPCL ṣi laipẹ yii ti dawọ iṣẹ duro o, paroparo nibẹ da bayii

Ireti awọn ọmọ Naijiria pe didun lọsan yoo so lori ọrọ epo bẹntiroolu pẹlu bi ileesẹ to n mojuto ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, NNPCL, ṣe sọ pe ileefọpo Naijiria to wa ni Portharcourt ti bẹrẹ iṣẹ, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii o, paro bii ode oro ni ileefọpo naa da. ALAROYE gbọ pe ko si awọn oṣiṣẹ nibẹ mọ, bẹẹ ni ko si awọn tanka nibi ti wọn ti n loodu epo, gbogbo rẹ gbẹ yau ni.

Nigba ti ọkan ninu awọn akọroyin iweeroyin Punch to ṣabẹwo sileefọpo naa n jabọ, o ni awọn oṣiṣẹ kan toun ba nibẹ sọ pe ayẹwo n lọ lọwọ, awọn si n wo awọn ohun eelo ti wọn fi maa n wọn awọn nnkan nibẹ lati ri i pe o wa nipo to yẹ ko wa, eyi ti wọn ni yoo gba awọn to ọsẹ kan gbako kawọn too pari eleyii.

ALAROYE gbọ pe ọkan ninu awọn oṣiṣẹ to wa nibẹ ṣalaye fun akọroyin naa pe ko si iṣẹ kankan to n lọ nileefọpo naa bayii o. O ni awọn tanka ti wọn ni wọn loodu epo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee,  yẹn, awọn epo ti wọn ti kọ̀ ti sinu awọn agba epo naa lati ọjọ to ti pẹ ni wọn loodu lọjọ ọhun.

O fi kun un pe ko too di pe wọn ti ileefọpo naa lọdun 2015 si 2016, awọn epo kan wa ninu tanki yii ti wọn ti kọ ti latigba naa ti ko sẹni to debẹ, ninu ẹ ni epo bẹntiroolu tawọn tanka epo gbe lọjọ Iṣẹgun yii.

Ọkunrin naa ni, ‘’Epo atijọ to ti pẹ to ti wa ninu tanki ni wọn gbe jade. Lẹyin ti wọn ti gbe awọn epo yii jade, wọn yoo nilo lati fọ awọn agba epo naa, ki wọn ko gbogbo awọn gẹdẹgẹdẹ epo to wa nibẹ kuro, ki wọn si tun un pa a laro ko too di pe wọn yoo ṣẹṣẹ maa gbe epo tuntun si i.

‘’Gbogbo ohun ti wọn n gbiyanju lati ṣe nileefọpo yii jẹ ti atijọ, ki i ṣe ti aye imọ ẹrọ ta a wa nisinyii, nitori pe o si jẹ ti atijọ, ko le ṣiṣẹ bii ti aye ode oni. Niṣe ni wọn kan tun gbogbo awọn ohun eelo ti wọn lo yii pa laro, ki i ṣe tuntun’’.

O ni nigba ti ọga agba patapata fun ileeṣẹ NNPCL, Mele Kyari, ṣabẹwo sileefọpo naa lọjọ Iṣẹgun, tanka ọkọ epo meje ni wọn ti ṣeto silẹ lati fi gbe epo, ṣugbọn marun-un pere ni wọn ri da epo si ninu rẹ, nitori epo ọhun ko ju bẹẹ lọ.

ALAROYE gbọ pe titi aago kan aabọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, ti akọroyin naa kuro nibẹ, ọpọ awọn oṣiṣẹ yii kan wa nileefọ naa ni, wọn ko fi bẹẹ ri nnkan ṣẹ. Ohun ti awọn kan ninu wọn sọ ni pe niṣe ni awọn n gbọn omi to wa nisalẹ epo naa pe boya o ṣee ṣe ki awọn ri epo gbe lẹyin eleyii, bo tilẹ jẹ pe o ni ko ti i si idaniloju.

Bii tanka epo mẹsan-an to jẹ tileeṣẹ NNPC ni wọn paaki kalẹ, ṣugbọn niṣe ni ojuko ibi ti wọn ti n gba epo da wai wai, ko si epo, ko si sẹnikẹni nibẹ.

Ọkan ninu awọn eeyan Abule Alode, ni Eleme, nibi ti ileefọpo naa wa ṣalaye pe, ‘’Lẹyin ti wọn ṣe ayẹyẹ ati ajọyọ pe awọn ti n fọpo nileefọpo naa tan, ki lo waa ṣẹlẹ lẹyin igba yẹn, wọn sọ pe awọn ti n gbe epo jade, ṣugbọn inu atẹgun ni wọn n gbe epo ọhun si o, ati loju ewe awọn iweeroyin ti wọn ti n kede rẹ’’.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ni ariwo gba ilu kan lati ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo nilẹ wa, NNPCL, pe ileeṣẹ ifọpo ilẹ wa to wa ni Portharcourt ti bẹrẹ iṣẹ. Niṣe ni gbogbo ọmọ Naijiria fo fayọ, ti wọn si n kira wọn ku oriire. Ireti wọn ni pe pẹlu bi ileefọpo naa ti bẹrẹ iṣẹ yii, owo epo bẹntiroolu yoo walẹ, epo naa yoo si sun wa bọ nilẹ wa.

Afi bi Akọwe awọn alẹnulọrọ ọkan ninu awọn abule ti ileefọpo naa wa, iyẹn Alese Community Srakeholders, Ọgbẹni Timothy Mgbere, sọ pe, ‘’Ileefọpo Portharcourt yii ati ibi ti wọn n ja epo si ti wọn n pe ni depo, jẹ ọna kan pataki ti o n mu ọrọ-aje gbogbo adugbo yẹn rọṣọmu. Bi ibẹ yẹn ki i ṣee figba kan da, ti iṣẹ maa n lọ nibẹ jẹ anfaani nla fun awa eeyan agbegbe yii. Ṣugbọn bi gbogbo nnkan ṣe wa lọwọlọwọ yii, mi o ro pe idi kan wa to fi yẹ ki ajọyọ kankan waye nileefọpo yii, nitori ohun ti awọn oniroyin n gbe jade nipa ileefọpo yii yatọ si ohun to n ṣẹlẹ nibẹ.

O ti to bii igba meje ọtọọtọ ti NNPCL ti n sọ pe ileefọpo naa ti fẹẹ bẹrẹ iṣẹ, ṣugbọn ẹjẹ lawọn araalu n ri, wọn ko ri omira. Eyi ni inu ọpọ awọn eeyan ṣe dun nigba ti wọn kede pe awọn yoo bẹrẹ si i gbe epo nibẹ lati ọjọ Iṣẹgun. Ṣugbọn pabo lo jọ pe ileri naa ja si. Eyi to si n bi ọpọ ọmọ Naijiria ninu ni irọ bantabanta ti wọn n pa fun wọn gẹgẹ bi awọn eeyan ti ALAROYE ba sọrọ lori bi nnkan ṣe n lọ nipa ileeṣẹ ifọpo naa ṣe sọ.

Leave a Reply