Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti ijọba apapọ ti fagi le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale nilẹ yii, iyẹn Special Anti-Robbery Squard ta a mọ si SARS, Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti bẹrẹ ayẹwo ọpọlọ fawọn eeyan naa.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan lorukọ CP Enwonwu, lo ti sọ pe igbesẹ ọhun wa ni ibamu pẹlu ibeere awọn ọdọ ti wọn fẹhonu han laipẹ yii, ninu eyi ti wọn ti beere fun ayẹwo ọpọlọ fawọn ọlọpaa SARS nitori bi awọn kan ninu wọn ṣe n huwa ọdaran ti ko jọ tọmọluabi eeyan rara.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “oỌna mẹta layẹwo ọhun pin si, akọkọ ni ifọrọwanilẹnuwo lati mọ bi laakaye awọn ọlọpaa SARS atijọ yii ṣe pe si, ekeji ni ayẹwo ọpọlọ gan-an lati mọ awọn to ba ni ọdẹ ori ninu wọn, nigba ti ẹkẹta jẹ ayẹwo ẹjẹ lati mọ eyi to ba n jẹ ijẹkujẹ, mu ọti lile tabi fin egboogi oloro sagbari ninu wọn.
“Awọn akọṣẹmọṣẹ to mọ nipa ayẹwo mẹtẹẹta yii lo ti wa n’Ibadan bayii, ti wọn si ti n ba iṣẹ wọn lọ bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii.
“Bo tilẹ jẹ pe ọga wa patapataa, IGP Muhammad Adamu, ti fagi le awọn SARS, awọn naa ni wọn ni ka ṣayẹwo yii pẹlu erongba lati le awọn to ba fidi-rẹmi ninu ayẹwo yii danu, ka si le gbe awọn ọmọluabi inu wọn lọ si ẹka mi-in nitori iru wọn ṣi wulo fun iṣẹ aabo ilu daadaa.”
Eto ayẹwo to n lọ lọwọ yii lo ti bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2020 ta a wa yii, to ṣi n tẹsiwaju titi di ba a ṣe n kọroyin yii.
CP Enwonwu waa rọ awọn ara ipinlẹ naa lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro fun ipese aabo to fẹsẹ mulẹ, ki wọn si yago fun iwa idaluru ati ṣiṣe idajọ latọwọ ara wọn.