Stephen Ajagbe, Ilorin
Awọn alaṣẹ ileewe Gbogboniṣe, Ọffa Poli, ti le akẹkọọ ẹni ọdun mejilelogun kan to wa nipele HND 1, Ọladipọ Ọpẹyẹmi Juwọn, ẹni tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ilọrin ti ju ṣẹwọn oṣu mẹsan fẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara.
Alukoro ileewe naa, Ọgbẹni Ọlayinka Iroye, lo fidii rẹ mulẹ ninu atẹjade kan lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
O ni ohun ti Ọladipọ ṣe ta ko ofin to de akẹkọọ nileewe naa, ati pe ninu ofin akẹkọọ yoowu tile-ẹjọ ba ti fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi iwa ọdaran kan tabi omi-in ko le tẹsiwaju lati maa wa nileewe naa.
Nigba ti akẹkọọ naa foju bale-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, Adajọ Mahmood Abdulgafar paṣẹ pe ko lọọ ṣẹwọn tabi ko sanwo itanran, nitori pe gbogbo iwadii ti fi han pe loootọ ni ọdaran naa lọwọ ninu iwa jibiti ori intanẹẹti.
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, lo wọ akẹkọọ naa lọ sile-ẹjọ lori ẹsun jibiti.
Ọladipọ yii ni wọn lo pe ara rẹ ni Frank Tinna, arẹwa obinrin oyinbo alawọ funfun, to si fi ifẹ ẹtan lu oyinbo kan, Bernard Fontenot, ni jibiti lori ẹrọ ayelujara ninu oṣu kẹta, ọdun 2019, niluu Ilọrin, nipa gbigba ọgọrun-un meji le marundinlogoji dọla, ($235) lọwọ rẹ.
Lẹyin tile-ẹjọ ka ẹsun naa si i leti, Ọladipọ jẹwọ pe loootọ loun jẹbi.
Oṣiṣẹ EFCC kan, Enoch Onyedikachi, lo jẹrii si ẹsun ti wọn fi kan ọdaran naa niwaju adajọ.
Onyedikachi ṣalaye pe ọjọ keje, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, nileeṣẹ EFCC, ẹka tilu Ilọrin gba lẹta kan lati ọdọ awọn araalu Ọffa, ninu eyi ti wọn ti kegbajare sawọn lati ran wọn lọwọ lori ọrọ awọn onijibiti ori ayelujara ti ko jẹ kawọn gbadun laduugbo.
O ni lẹyin tawọn ya bo agbegbe naa lawọn ri olujẹjọ ọhun pẹlu awọn afurasi mi-in ko. Nigba tawọn si yẹ ara rẹ wo, awọn ba foonu olowo nla kan, iPhone lọwọ, eyi to fi n patu lori intanẹẹti.
Adajọ Abdulgafar ni ki ọdaran naa lọọ ṣẹwọn oṣu mẹsan-an tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna igba ataabọ, #250,000, lori ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi wọ ọ wa sile-ẹjọ.
Ile-ẹjọ ni ọdaran naa yoo bẹrẹ ẹwọn rẹ lati ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun yii, lati gba a laaye ko pari idanwo to n ṣe lọwọ nileewe rẹ.
Bakan naa, adajọ tun ni ijọba ti gbẹsẹ le foonu to n fi ṣe jibiti naa, o si tun paṣẹ pe ki ọdaran naa da owo to ti fọgbọn jibiti gba lọwọ awọn to ko si i lọwọ pada.