Imaamu rọ Adeleke: Ṣọra fawọn oniwa agabagebe lẹgbẹẹ rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iranṣẹ Ọlọrun kan, Imaamu Taofeek Abdulhammed, ti ke si gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lati ṣọra fun awọn alagabagede (sycophants) ti wọn yoo maa kan saara si i titi ti yoo fi ṣiṣe.

Nibi adura iberẹ ọdun tijọba ipinlẹ Ọṣun ṣagbekalẹ rẹ to waye ni ọfiisi ijọba ni Abere, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni Imaamu yii ti sọ pe awọn eeyan buru pupọ, ko si si nnkan ti wọn ko le ṣe lati fi wa ojurere aṣaaju.

O ran gomina leti oniruuru ileri to ṣe fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lọjọ ti wọn n ṣebura fun un, o ni majẹmu ni gbogbo ọrọ naa, ko si gbọdọ faaye gba awọn ti ko ni i jẹ ko ni afojusun lati mu wọn wa simuṣẹ.

Imaamu Abdulhammed, to jẹ ọga agba ileewe gbogboniṣe ijọba apapọ to wa niluu Ayede, nipinlẹ Ọyọ, sọ siwaju pe ki Gomina Adeleke ma ṣe jẹ ki agbara ọfiisi naa gun un, o ni awọn afoju-fẹ-ni-ma-fọkan-fẹ-ni yoo ṣugbaa yi i ka lasiko yii, ti wọn ko si ni i ri nnkan ti ko dara ninu ohunkohun to ba n ṣe.

O fi kun ọrọ rẹ pe gomina gbọdọ mọ pe itan ni onidaajọ agba, ohun gbogbo to ba si ṣe n lọ sinu akọsilẹ.

Nigba to n sọrọ, Gomina Adeleke ni ipinnu oun ni lati gbe ipinlẹ Ọṣun goke agba ni gbogbo ọna.

O ke si gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa lati ji giri si iṣẹ wọn. O ni ki wọn mu imọtoto lọkun-un-kundun, nitori oun yoo bẹrẹ si i ṣe abẹwo airotẹlẹ si awọn ọfiisi kaakiri bayii.

Leave a Reply