Stephen Ajagbe, Ilorin
Ṣọọbu mọkanla toun pẹlu ọja inu ẹ nijamba ina kan to ṣẹ yọ laarin oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, jo ninu Ọja Ipata, to wa niluu Ilọrin.
Agbegbe awọn to n ta eroja ọbẹ atawọn nnkan isebẹ mi-in bii ẹja ati bẹẹ lọ lo fara gba iṣẹlẹ naa ju.
ALAROYE gbọ pe ko si ẹnikankan nitosi tabi ninu ọja naa lasiko ti ina ti wọn ko mọ ibi to ti ṣẹ yọ naa bẹrẹ, idi niyi to fi jo awọn ṣọọbu naa ko too di pe wọn fi to ileeṣẹ panapana leti.
Akitiyan awọn oṣiṣẹ panapana to lọ sibẹ lo mu ki wọn tete ri ina naa pa ko too di pe o ran awọn ṣọọbu bii ọgọrun-un marun-un to wa ninu ọja naa.
Alukoro ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara, Hakeem Hassan Adekunle, ni Ọgbẹni Hawali lo pe awọn lori foonu lati fi iṣẹlẹ naa to awọn leti.
O ni loootọ niroyin iṣẹlẹ naa pẹ ko too kan awọn lara, ṣugbọn to ba jẹ pe awọn ko debẹ lasiko yẹn, o ṣee ṣe ko jẹ gbogbo ọja naa lo maa jona patapata.