Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi a ba peri aja, dandan ni ka peri ikoko ti wọn fi se e lọrọ da bayii fun DPO ọlọpaa tẹsan Lafẹnwa, nitori Gomina Dapọ Abiọdun ti fibinu ẹ han sọkunrin naa latari ina to ṣẹ yọ lọja Lafẹnwa, l’Abẹokuta, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn gbe DPO naa kuro ni Lafẹnwa kia, ki Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Lanre Bankọle, wa ibomi-in gbe e lọ.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni gomina paṣẹ naa, nigba to ṣabẹwo si Lafẹnwa ti ijamba ti ṣẹlẹ, ti eeyan meji jona ku, tawọn ọlọja si ṣofo ọpọlọpọ ọja olowo iyebiye sinu ina ọhun.
Nipa ti DPO ti Abiọdun ni ki wọn paarọ ẹ, o sọ nipa ọlọpaa naa pe o pẹ tawọn eeyan ti n ṣaroye nipa ẹ pe ki i ṣe ọmọluabi. O loun gbọ pe DPO naa n ṣọrẹ awọn ọdaran, to bẹẹ to jẹ ti wọn ba mu ọdaran de ọdọ rẹ bayii, laarin iṣẹju marun-un si mẹwaa ni yoo ti fi wọn silẹ, lẹyin tawọn iyẹn ba ti wa nnkan fun un. O ni nitori ẹ ni Lafẹnwa ko ṣe sinmi lọwọ awọn ọmọkọmọ.
Gomina tẹsiwaju pe iru iwa buruku bẹẹ naa lo tun ṣẹlẹ lọjọ ti ina ṣẹ yọ lọja Lafẹnwa yii. O ni nigba ti tanka to gbe epo ṣubu, ti epo inu rẹ si rọra n da si koto idaminu, ti awọn ẹṣọ alaabo si n ṣiṣẹ wọn lati dẹkun ina tabi wahala kan, to waa jẹ pe awọn ọmọkọmọ kan ni wọn mọ-ọn-mọ sọna si tanka naa ti ina nla fi sọ.
To bẹrẹ si i jo hii hii, to pa awọn ẹni ẹlẹni ti ko mọwọ mẹsẹ, to tun sọ ọpọ ọlọja dẹni ti ko ni nnkan kan nisọ mọ.
Ọmọọba Abiọdun sọ pe nitori awọn ọmọ ganfe naa ti mọ pe awọn ni baba nigbẹẹjọ ni wọn ṣe sọna si tanka, ṣugbọn ni bayii, ki wọn gbe DPO to n ṣegbe lẹyin wọn naa kuro, ki wọn wadii ẹ finni-finni, ki wọn si wa awọn ọmọkọmọ to sọna si tanka epo naa ri pẹlu.
Bakan naa ni gomina ba awọn to padanu eeyan wọn kedun, pẹlu awọn ọlọja ti wọn ṣofo ọja olowo iyebiye.
O ni ki kọmiṣanna to n ri si awọn akanṣe iṣẹlẹ bii eyi ṣe akọsilẹ awọn nnkan to ṣofo lọja Lafẹnwa, bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo fun awọn ọlọja naa ni nnkan iranwọ diẹ lati fi dun wọn ninu.
Ọjọ mẹta ni Gomina fun TRACE ati kọmiṣanna fun igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, lati fi ṣewadii ohun to fa ina naa gan-an.
Tẹ o ba gbagbe, aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ni iroyin ina to ṣẹ yọ ni Lafẹnwa naa jade sita, to jẹ iya agba kan ati ọmọ-ọmọ ẹ jona ku sibẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn kan sọ pe eeyan to jona ku to mẹrin.
Nigba tawọn panapana ati TRACE si tun n ba iṣẹ wọn lọ lati kapa ina ọhun, niṣe lawọn ọmọ ganfe kan tun kọ lu wọn, wọn ba mọto TRACE jẹ, bẹẹ naa ni wọn ṣe fun ọkọ awọn oṣiṣẹ panapana.