Monisọla Saka
Ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ẹka ti ipinlẹ Delta, ti kọ lati gba esi idibo aarẹ ti ijọba ibilẹ ti igbakeji aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, to tun jẹ gomina nipinlẹ ọhun, Ifeanyi Okowa, ti wa.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, lawọn ajọ ọhun fariga pe awọn ko le gba esi idibo ti wọn ko wa sile iṣẹ awọn to wa niluu Asaba, olu ilu ipinlẹ naa nitori adiju ibo, wọn sọ pe wọn dibo ju bo ṣe yẹ lọ lagbegbe ijọba ibilẹ ọhun. Eyi ni pe iye esi ibo ti wọn ko wa siwaju ajọ INEC pọ ju iye eeyan to forukọ silẹ nibẹ lọ.
Ijọba ibilẹ Ika North-East, ti Gomina Okowa ti i ṣe oludije fun ipo igbakeji aarẹ lẹgbẹ PDP ti wa, wọn ni magomago wa ninu esi idibo ti wọn ko jọ nibẹ. Ọga agba to n ṣe kokaari esi idibo nipinlẹ Delta, Ọjọgbọn Abraham Georgewill Owuneri, sọ pe ajọ INEC ko ni i gba awọn esi naa nitori pe iye awọn eeyan ti wọn forukọ silẹ, tawọn si buwọ lu, yatọ si iye esi ibo ti wọn gbe siwaju awọn.
Ninu esi idibo ti oṣiṣẹ ajọ INEC, ẹkun ijọba ibilẹ Ika North-East, Dokita James Olisa, gbe siwaju ajọ INEC, iye awọn oludibo ti wọn fọwọ si lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, fun ibo aarẹ lagbegbe naa jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn ati ọgọrun-un o le marun-un (30,105), ti iye ibo ti wọn di si jẹ ẹgbẹrun lọna mọkanlelọgbọn ati ẹgbẹta o le mọkanlelọgọrin (30,681).
Amọ ṣa, esi ibo ijọba ibilẹ Ika ti ajọ INEC kọ yii, wọn lo fi han pe ẹgbẹ oṣelu Gomina Okowa lo wọle nibẹ, nigba ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party tẹle e, ti ẹgbẹ APC si ni ibo to kere ju lọ nijọba ibilẹ ọhun.