INEC wọgi le ikede esi atundi ibo gomina nipinlẹ Adamawa

 Faith Adebọla

Ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), ti paṣẹ pe ikede ti Ọga agba ajọ INEC nipinlẹ Adamawa, iyẹn Resident Electoral Commissioner (REC), Amofin Hudu Yunusa, ṣe laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ta a wa yii, pe oludije funpo gomina lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Sẹnetọ Aishatu Dahiru lo gbegba oroke ninu atundi ibo to waye, to si kede rẹ gẹgẹ bii gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, wọn ni ikede naa ko bofin mu, awọn si ti wọgi le e lẹyẹ-o-sọka.

Bakan naa ni wọn paṣẹ pe ki oludari eto idibo sipo gomina ọhun (Returning Officer), ti wọn loun lo yẹ ko kede esi idibo atẹni to jawe olubori, maa ko gbogbo iwe idibo ati eroja to wa nikaawọ rẹ bọ ni olu-ileeṣẹ INEC, l’Abuja, lai sọsẹ.

Lori ikanni abẹyẹfo, tuita ni ajọ eleto idibo ti fi atẹjade kan lede, eyi ti Amofin Festus Okoye ti i ṣe alakooso eto iroyin ati ilanilọyẹ ajọ naa buwọ lu, lọjọ Aiku, Sannde, kan naa.

Atẹjade naa ka pe:

“O ti de akiyesi wa pe ẹni to jẹ ọga agba ajọ INEC nipinlẹ Adamawa, ti kede ẹni to jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina ipinlẹ naa nigba ti akojọ esi idibo naa ko ti i pari, ti iṣiro ati aropọ ibo si ṣi n lọ lọwọ.

“Ohun ti REC yii ṣe yii, aṣilo ipo ni, tori niṣe nigbesẹ naa ta ko agbara adari eto idibo, iyẹn Returning Officer. Latari eyi, gbogbo ikede ti REC naa ṣe ko bofin mu, ko lẹsẹ nilẹ, otubantẹ ati ofifo lasan ni.

“Ni bayii, a paṣẹ ki eto kika, kikojọ, ṣiṣe iṣiro ati aropọ idibo to waye naa ṣi duro na.

“A fi asiko yii ke si ọga agba ti wọn lo ṣe ikede ti ko bofin mu yii ati adari eto idibo, iyẹn Returning Officer, ati gbogbo awọn tọrọ idibo naa kan, lati maa bọ taara si olu-ileeṣẹ ajọ INEC to wa l’Abuja. Ko gbọdọ si ijafara kankan lori eyi.

“A o maa sọrọ siwaju si i nipa iṣẹlẹ yii laipẹ.”

Bayii ni ikede naa ṣe lọ.

Ẹ oo ranti pe niṣe ni INEC pe fun atundi ibo lori eto idibo sipo gomina ipinlẹ Adamawa to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, nigba ti awuyewuye waye lori esi idibo naa, ti ẹri si fihan pe ko sẹni to gbegba oroke nibaamu pẹlu ofin ati alakalẹ eto idibo, laarin awọn ẹgbẹ oṣelu meji to lewaju ju lọ, iyẹn APC ati PDP.

Ninu esi idibo ti wọn kede rẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta yii, Binani to jade labẹ APC ti ni ibo to din diẹ lẹgbẹrun lọna irinwo (390,275) nigba ti Gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ, Ahmed Fintiri, to dije labẹ ẹgbẹ Alaburada (PDP), lati le wọle saa keji nipo, ni ibo to fi ẹgbẹrun lọna ọgbọn ju ti Binani lọ, ibo 421,524 lo wa lakọọlẹ fun un.

Amọ nitori awọn ibudo idibo bii mọkandinlaaadọrin (69), nibi ti wọn ti wọgi le esi idibo wọn, boya nitori ija ati iwa janduku to ṣẹlẹ, tabi ti ko ṣee ṣe lati dibo rara, eyi ti wọn ni aropọ iye oludibo wọn to ẹgbẹrun mẹtadinlogoji (37,016), eyi lo mu ki wọn paṣẹ pe ki atundi idibo waye lawọn ibudo wọnyi, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii.

Nibi ti wọn ṣi kede esi idibo naa de, Gomina Fintiri lo n lewaju ninu atundi idibo ti wọn ti ka.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni Ọga ajọ INEC l’Adamawa yii, Hudu Yinusa, kan ṣadeede yan bii ologun wọnu gbọngan ti wọn ti n ṣiro esi idibo lọwọ, to si bẹrẹ si i sọrọ fatafata sinu ẹrọ amohun-bu gbẹmu pe Binani ti gbegba oroke, amọ ko sọ iye ibo ti obinrin naa ni, bẹẹ ni ko sọ pe oun laṣẹ lati ṣe ikede yii.

Ikede ọhun ti mu ki Binani ba awọn oniroyin sọrọ idupẹ, o ni inu oun dun p’oun yege, ati pe oun ni yoo di gomina obinrin akọkọ ninu itan orileede Naijiria, bẹẹ si lọrọ naa ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara.

Amọ ninu fidio mi-in ti wọn fi han lori intanẹẹti, awọn agbofinro ti mu Yinusa. Ṣaaju ki wọn too mu un, ni wọn lawọn janduku kan tinu bi si ikede to ṣe ọhun ti kọkọ lu u, wọn bọṣọ lọrun ẹ, wọn gba ṣokoto nidii rẹ, o si ku pata nikan, bẹẹ lẹjẹ n jade nibi ẹnu rẹ, to n kan si i laya. Lẹyin eyi ni wọn lawọn ọtẹlẹmuyẹ kan ti fi pampẹ ofin gbe e lọ sakata wọn.

Ni bayii ti wọn ti wọgi le ikede awuruju tọkunrin yii ṣe. Abajade esi idibo naa, eyi ti ireti wa pe wọn yoo yanju rẹ lolu-ileeṣẹ INEC, lawọn eeyan n duro de.

Leave a Reply