Faith Adebọla, Eko
Pẹlu bi ero pitimu ṣe n lọ ti wọn n bọ lagbegbe ọja igbalode Computer Village, to wa n’Ikẹja, sibẹ awọn gende mẹta ti wọn fura pe gbọmọgbọmọ ni wọn yii ra pala sinu gọta lati ṣiṣẹ ibi, ṣugbọn ibẹ ni wọn ka wọn mọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, niṣẹlẹ naa waye. Inu gọta to wa labẹ biriiji to gba ọna Awolọwọ kọja si ọna Mobọlaji Bank-Anthony, niwaju ọja kọmputa ọhun lọwọ ti ba awọn afurasi naa.
Ontaja kan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ, Biọdun Adedeji, sọ f’ALAROYE pe eeyan o tiẹ le ronu pe ẹda Ọlọrun kan le wa ninu gọta naa, ẹnikan lo ri ọkan ninu awọn afurasi naa, wọn kọkọ ro pe boya nnkan ja bọ lọwọ ẹ sinu gọta yẹn ni, afi igba tawọn eeyan bẹrẹ wo o ni wọn ba ri i pe awọn mẹta lo wa nibẹ.
Oju-ẹsẹ lero ti pe le wọn lori pe ki wọn jade, kaka ki wọn jade, niṣe lawọn mẹtẹẹta fere ge e labẹ gọta ọhun, ti wọn fẹẹ lọọ gba odikeji jade. Ṣugbọn awọn ọdọ to wa nitosi tọpasẹ wọn, bẹẹ ni wọn n juko lu wọn, ti wọn n fi igi atawọn nnkan mi-in di wọn lọna lati ma ṣe ribi sa lọ.
Nigbẹyin, ọna pin mọ wọn, ni wọn ba wọ wọn jade. Bidemi ni wọn ba oogun abẹnu gọngọ lara wọn, ọbẹ aṣooro ati aake meji, nigba ti wọn mu wọn.
Awọn ọlọpaa lati teṣan Area ‘F’ to wa nitosi ni ko jẹ kawọn ọdọ naa ṣe ṣege fawọn afurasi ọdaran yii, wọn tete ko wọn lọ si teṣan wọn.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ti taari awọn amookun-ṣika ẹda naa sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹu.
Adejọbi ni awọn maa wọ wọn de kootu laipẹ, bẹẹ lo rọ awọn araalu lati tubọ wa lojufo si ohunkohun to ba n ṣẹlẹ lagbegbe wọn, ki wọn si tete maa fi to ọlọpaa leti ti wọn ba ri ẹnikẹni ti irin rẹ mu ifura lọwọ.