Adewale Adeoye
Bi wọn ba n wa ọdaran-mọran ẹyẹ to n mu ọsan lori iso, apẹẹrẹ rẹ gan-an ni Rasheed Bọlaji, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, kan to wa ninu ọgba ẹwọn Ikoyi, niluu Eko. Ko ti i bọ ninu ẹwọn to n ṣe ti adajọ fi tun fi ọdun meji mi-in kun un fun un. Eyi ko sẹyin bi ọmọkunrin naa ṣe tun n ta igbo fawọn ẹlẹwọn ẹgbẹ ẹ. N ladajo ba tun fi ọdun meji kun iye ọdun to yẹ ko lo lọgba ẹwọn.
ALAROYE gbọ pe ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe oogun oloro nilẹ wa, (NDLEA) lo ka igbo mọ ọmọkunrin naa lọwọ lọgba ẹwọn Ikoyi to wa, ni wọn ba fọwọ ofin mu un, eyi lo tun sọ Rasheed dero kootu, to fi n kawọ pọnyin niwaju adajọ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe wọn ba oogun oloro nikaawọ rẹ.
Nigba ti agbẹjọro NDLEA, M.I Eronidu, n sọrọ ni kootu, o ni, ‘Iwọ Rasheed Bọlaji, ajọ to n gbogun ti tita ati lilo oogun oloro (NDLEA) ba egboogi oloro lọwọ rẹ ninu ọgba ẹwọn to wa n’Ikoyi, niluu Eko, lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2022, nibi to o ti n ta a fawọn onibaara rẹ kan ti awọn naa jẹ ẹlẹwọn bii tiẹ. Iwa ọdaran naa ta ko ofin ilu Eko, ati ti orile-ede wa lapapọ patapata, ijiya nla si wa fun ẹni yoowu tọwọ ba tẹ pe o ṣe iru nnkan bẹẹ lawujọ wa.’
Oriṣii ẹsun iwa ọdaran meji ọtoọtọ ni wọn fi kan Rasheed. Ẹsun akọkọ ni pe o n ta igbo ninu ọgba ẹwọn, ati pe niwọn igba to jẹ pe o ṣi wa ninu ọgba ẹwọn naa, ko lẹtọọ rara labẹ ofin lati maa ṣe okoowo kankan rara.
Agbefọba ni ki adajọ wo inu iwe ofin ilẹ yii, ko si ṣe amulo idajọ to ba tọ fun olujẹjọ lori iwa radarada to hu naa.
Loju-ese ni ọmọkunrin yii ti n rawọ ẹbẹ si adajọ pe ko ṣiju aanu wo oun, nitori pe igba akọkọ ree toun maa ṣiwa-hu ninu ọgba ẹwọn naa latigba toun ti n ṣẹwọn nibẹ. O ni oun ko tun jẹ dan iru iwa bẹẹ wo mọ laelae.
Nigba to n gbẹnu rẹ sọrọ, Agbẹjọro Rasheed, Bọlanle Kọlawọle, rọ adajọ ile-ẹjọ naa pe ko ṣiju aanu wọ onibaara oun, o ni idi pataki to ṣe n mu igbo naa nigba gbogbo ni pe iṣẹ awọn to n mọle (Bricklayer) lo n ṣe, o si nilo agbara daadaa lati maa fi ṣiṣẹ naa deede. Bakan naa lo ni ki adajọ naa faye beeli silẹ fun onibaara oun, ki ijiya naa le dinku jọjọ.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Abimbọla Awogboro fi ọdun meji kun ọdun Rasheed Bọlaji ninu ọgba ẹwọn to wa, o si kọ lati faaye beeli silẹ fun un.