Faith Adebọla, Eko
Ahamọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lawọn afurasi adigunjale meji kan, Tunji Lawal ati Ikechukwu Oguawai, tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mejilelogun wa bayii. Eyi ko sẹ́yìn bi wọn ṣe lọọ fibọn jale ninu ọgba ileewe kan l’Ekoo, tọwọ si tẹ wọn.
Ọsan gangan, ni nnkan bii aago meji, ọjọ Abamẹta, Satide, lawọn adigunjale yii fo fẹnsi ọgba ileewe Amuwo Ọdọfin Senior Grammar School, wọn si bẹrẹ si i ṣakọlu sawọn akẹkọọ to n ṣẹdanwo aṣekagba wọn lọwọ, bẹẹ ni wọn n fibọn gba dukia awọn obi to mu awọn ọmọ wọn wa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Olumuyiwa Adejọbi, to fọrọ yii to ALAROYE leti sọ pe awọn adigunjale naa pọ, niṣe ni wọn kọkọ n da awọn obi to mu ọmọ wa fun idanwo aṣepari pamari ti wọn n pe ni Common Entrance, lọna, ti wọn si n gba dukia wọn bii foonu, owo ati nnkan ọṣọ ara wọn.
Awọn kan ti wọn fura si nnkan to n ṣẹlẹ ni wọn lọọ ta wọn ọlọpaa ti wọn yan sibi idanwo naa lolobo, ṣugbọn kawọn ọlọpaa naa to debi tawọn afurasi yii ti n ṣiṣẹẹbi wọn, awọn kan ti gba ọna ẹyin lati lọọ kọ lu awọn akẹkọọ to n ṣedanwo lọwọ naa. Bi wọn ṣe kẹẹfin awọn ọlọpaa ni wọn sa lọ. Ori ere ọhun lọwọ ti ba Tunji ati Ikechukwu.
Adejọbi lawọn mejeeji yii ti jẹwọ pe loootọ lawọn waa digunjale nileewe naa, ṣugbọn dukia ati owo lawọn ba wa, awọn obi to mu ọmọ wa lawọn fẹẹ da lọna. Wọn tun jẹwọ pe awọn pọ tawọn digun waa jale ọhun. Nigba ti wọn wadii ile ti wọn n gbe, wọn ni wọn o ni adirẹsi gidi kan pato, ko jọ abẹ biriiji ati gareeji ni wọn n sun kiri, bi wọn ṣe wi.
Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn meji tọwọ ba yii si ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin nipa wọn. Bẹẹ lo tun paṣẹ pe kawọn agbofinro ṣawari awọn to sa lọ naa, tori gbogbo wọn gbọdọ kawọ pọnyin rojọ ni kootu laipẹ.