Inu ọkọ akọtami ni Inspẹkitọ Ahmed fẹẹ dọgbọn wọ ti awọn adigunjale fi fibọn fọ ọ lori n’Iragbiji

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin ọlọpaa kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Inspẹkitọ Ahmed lo ba iṣẹlẹ idigunjale to waye ni banki Wema ilu Iragbiji, nijọba ibilẹ Boripẹ lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ilu abinibi gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ni Iragbiji jẹ, iṣẹlẹ yii si ṣẹlẹ laarin oṣu meji ti awọn adigunjale ṣoṣẹ ni banki Access ati UBA to wa niluu Iree, nibi ti wọn ti pa Kọstabulari Jẹlili Aladeọkin.

Titi di ọsan oni tiṣẹlẹ idigunjale yii waye, ileefowopamọ Wema ti ilu Iragbiji yii nikan lo ku fun awọn eeyan ijọba ibilẹ Boripẹ ati Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ṣe ni awọn adigunjale yii pin ara wọn si mẹta, ẹẹkan naa si ni wọn ṣọṣẹ ni banki naa ati agọ ọlọpaa to wa lẹgbẹẹ rẹ pẹlu ọfiisi awọn ọlọpaa to n mojuto irinkerindo ọkọ nitori agbegbe Oniyere yii ni gbogbo wọn wa.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ko ti i ju ọgbọn iṣẹju ti ọkọ agboworin wọnu banki naa lawọn eeyan naa de, wọn si kọkọ fi iro ibọn ko gbogbo awọn to n rin oju-ọna Ikirun si Ada laya jẹ ki wọn too bẹrẹ iṣẹ.

Bakan naa la gbọ pe inu agọ ọlọpaa ni Inspẹkitọ Ahmed wa nigba ti awọn adigunjale naa de, ṣe ni jinnijinni si ba gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn wa nibẹ nigba ti ibọn n dun lakọlakọ.

Wọn ni Ahmed paapaa ko mura silẹ rara, ṣugbọn ibi ti iṣẹlẹ naa ba a ko jinna si ibi ti wọn gbe ọkọ akọtami (Armoured Personnel Carrier) si, ṣe lo si fẹẹ dọgbọn wọnu ọkọ naa ti awọn adigunjale ọhun fi gbebọn fun un lori mọ oju, to si gbẹmii mi loju ẹsẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni idigunjale naa waye, ṣugbọn awọn n ṣiṣẹ lati tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ naa lọwọ.

O ni awọn ọlọpaa ti wa lagbegbe ọhun lati ṣawari awọn adigunjale naa nibi ti wọn ba sa pamọ si.

Ṣugbọn ninu ọrọ tirẹ, Agbẹnusọ ajọ Sifu Difẹnsi l’Ọṣun, Daniel Adigun, sọ pe eeyan kan, ti awọn ko ti i mọ bo ṣe jẹ, ku ninu iṣẹlẹ idigunjale naa.

Adigun fi kun ọrọ rẹ pe bọọsi meji to jẹ elero-mejidinlogun ni awọn eeyan naa gbe wa, ti wọn si pin ara wọn kaakiri. O ni lẹyin ti wọn pitu ọwọ wọn tan ni wọn sa gba ọna Ada si Ibokun lọ.

Leave a Reply