Inu oko lawọn ọdọ kan ti n ṣiṣẹ tawọn agbebọn fi ko ọgọrin lọ ninu wọn

Adeoye Adewale

Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ, awọn janduku agbebọn ti ko sẹni to mọ ibi ti wọn wa bayii ti tun lọọ ji awọn ọmọ keekeeke ti iye wọn to ọgọrin (80Children) ni agbegbe Tsafe, nijọba ibilẹ Tsafe, nipinlẹ naa bayii.

Koko ohun ti wọn fẹẹ gba, yala lọwọ awọn obi awọn ọmọ naa tabi ijọba ni ko sẹni to ti i mọ. Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ naa si ti sọ pe awọn ko gburoo wọn rara ninu igbo nla kan ti wọn ko gbogbo wọn gba, ṣugbọn wọn ṣẹlẹri pe iṣẹ n lọ labẹnu bayii lati fọwọ ofin mu awọn janduku agbebọn naa ni kia.

Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe laaarọ kutukutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹrin yii, ni awọn agbebọn naa ti iye wọn ko lonka ya wọnu oko kan bayii, nibi ti awọn ọmọ naa ti ọjọ ori wọn ko ju ọmọọdun mejila si mẹtadinlogun lọ (12-17) ti n ba awọn obi wọn ṣiṣẹ oko lọwọ, ti won fipa ko gbogbo wọn wọnu igbo kijikiji kan lọ.

Gbogbo ẹbẹ tawọn obi awọn ọmọ naa n bẹ awọn janduku yii ni wọn ko gbọ rara, ti wọn si ṣẹ bẹẹ ko wọn lọ patapata.

Ọkan lara obi awọn ọmọ ohun to gba lati ba ileeṣẹ iroyin BBC ede Hausa sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe awọn ko mọ rara pe awọn eeyan ọhun ti lugọ sẹgbẹẹ oko awon, niṣe ni wọn kan yọ sawọn lojiji, ti wọn si ji gbogbo awọn ọmọ to wa ninu oko lọjọ naa gbe sa lọ patapata.

Ijọba ipinlẹ Zamfara ko ti i sọrọ rara lori iṣẹlẹ naa, bẹẹ ni wọn ko sọ pe iṣẹlẹ naa ko waye.

Ohun to jẹ ki ọrọ awọn agbebọn naa ru awon eeyan loju, paapaa ju lọ  awọn to mọ iye owo nla ti ijọba ipinlẹ naa ti na lati dẹkun iwa ọdaran wọn ni wọn n sọ pe ejo awọn agbebọn yii lọwọ ninu.

 

Leave a Reply