Aderohunmu Kazeem, Eko
Awọn ọkunrin meji kan ti wa lọdọ ọlọpaa nipinlẹ Eko bayii lori ẹsun pe wọn ja mọto Toyota Corrolla gba lọwọ Utibe, to n ba ileeṣẹ to n fi mọto ayọkẹlẹ ṣe taksi ṣiṣẹ.
Agbegbe Ibẹju-Lekki la gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn ọkunrin meji yii, oju oorun gan-an ni wọn wa nigba tawọn ọlọpaa ba wọn ninu mọto naa.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an ku bii ogun iṣẹju ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni awọn ọrẹ meji yii ba awakọ ọhun sọrọ lori ẹrọ ayelujara pe ko waa gbe awọn lọ sibi kan. Ninu irin-ajo naa ni wọn ti fi ohun ijamba ẹlẹnu ṣoṣoro gun un, ti wọn si gbe mọto rẹ lọ.
Nibi ti wọn ti n sa lọ ni ọkọ ayọkẹlẹ yii ti taku mọ wọn lọwọ, ti wọn si lero pe epo lo tan mọ ọn lẹnu. Ninu mọto ọhun lawọn mejeeji sun si, nibẹ naa ni awọn ọlọpaa ka wọn mọ, ti wọn si ti dero atimọle bayii.
Agẹbnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, fidi iṣẹlẹ naa mule, o ni LND 448 GH. ni nọmba idanimọ ọkọ ọhun. Bakan naa lo sọ pe ọkunrin awakọ naa ti n gba itọju lọsibitu bayii, tawọn ọdaran ọhun si wa ni akolo awọn.