Faith Adebọla, Eko
Ọmọọdun mẹẹẹdogun pere ni Sunday Dare ati Ayọmide Sanni Babatunde, ọmọọdun mẹrinla ni Ọlayinka Jubril ni tiẹ, Tosin Balogun lo ti pe ọmọ ọdun mejidinlogun, ṣugbọn ohun kan to da gbogbo wọn pọ yatọ si pe ọjọ ori wọn o ti i pe ogun ọdun ni pe, ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun lawọn mẹrẹẹrin lati ipinlẹ Ogun, ọwọ ọlọpaa si ti ba wọn l’Ekoo lọjọ Ẹti, Furaidee.
ALAROYE gbọ pe ileewe girama ti wọn n pe ni Ọdẹwale Community High School, niluu Ijoko, nipinlẹ Ogun, ni wọn ni Tosin ati Jubril n lọ, Babatunde n lọ sileewe aladaani Tunik International School, to wa lagbegbe Dalekọ, nipinlẹ Ogun, kan naa, ṣugbọn ọmọ ẹkọṣẹ ni Dare Sunday, iṣẹ telọ ni wọn loun n kọ lọwọ ni Dalekọ.
Olobo kan lo ta awọn agbofinro nipa igbesẹ ti wọn lawọn afurasi ọdaran yii fẹẹ gbe to jẹ ki wọn ri wọn mu, wọn lawọn ọmọ wọnyi n mura ija, wọn fẹẹ lọọ gbẹsan lara awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun mi-in ti wọn wa nileewe Junior Secondary School, laduugbo Akinyẹle, l’Alakukọ, nipinlẹ Eko.
Bawọn ọlọpaa ṣe gbọ nipa ọrọ yii ni wọn tete lọ sileewe JSS, Alakukọ ti wọn darukọ ọhun, awọn ọlọpaa ti o wọṣọ ni o, wọn lugọ de awọn afurasi yii, ọwọ si ba wọn ki wọn too dana ijangbọn sileewe naa.
Boya tori iṣẹ dudu ti wọn fẹẹ ṣe ni o, boya yunifọọmu ẹgbẹ wọn si ni, ẹwu polo dudu kirimu lawọn mẹta ninu wọn wọ lọjọ Ẹti, Furaidee tọwọ tẹ wọn.
Iyalẹnu lo jẹ pe bi wọn ṣe mu wọn, ti wọn yẹ ara awọn ọmọ ti awọn obi n run owo le lori lati kawe wọnyi wo, wọn ba ada mọnbe oriṣiiriṣii, egboogi oloro ti wọn fura pe igbo ni, awọn oogun abẹnu gọngọ ti wọn faṣọ pupa we, ọbẹ aṣooro atawọn nnkan ija mi-in ni wọn n ko kiri.
Nigba tawọn ọlọpaa n beere ọrọ lọwọ wọn, awọn majeṣin ẹlẹgbẹkẹgbẹ yii jẹwọ pe ko ti i pẹ tawọn dọmọ ẹgbẹ okunkun, wọn ni ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn to wa nileewe JSS ni awọn kan fiya jẹ, tori kawọn le ba a kọya lawọn ṣe wa.
Wọn lawọn o ni i lọkan lati da wahala silẹ o, tori awọn ti kọkọ wa sileewe naa tẹlẹ, awọn si ti sami si awọn tawọn fẹẹ kọ lu, awọn tawọn ba lẹjọ lawọn fẹẹ fiya jẹ.
Ṣa, ọlọpaa ti ko awọn mẹrẹẹrin, wọn si ti taari wọn sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ẹka kan wa nibẹ to n bojuto ọrọ awọn majeṣin to ya ipanle, ibẹ ni wọn ko wọn lọ, iṣẹ iwadii si ti n lọ lori wọn bayii.