Ipinlẹ Ogun ni Babatunde atọrẹ ti ji mọto, lasiko ti wọn fẹẹ ta a n’Ilọrin lọwọ tẹ wọn

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

 

 

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Bagega Lawal, ni awọn afurasi mẹfa ọtọọtọ lọwọ awọn tẹ laarin oṣu kin-in-ni, ọdun yii, fun oniruuru ẹsun kaakiri ipinlẹ naa.

Bagega sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. O ni ọkan lara wọn, Akinṣọla Babatunde, tawọn eeyan mọ si ‘Mr White’ ti wọn fẹsun kan pe o pe pati onihooho niluu Ilọrin.

Akinṣọla to n gbe Ojule kẹrindinlogun, Opopona Achimugun, lagbegbe Flower Garden, niluu Ilọrin, ni ọlọpaa fẹsun kan pe oun atawọn ẹgbẹ rẹ kan maa ṣe pati, nibi tawọn obinrin yoo ti maa jo nihooho lawọn ile-ijo ati ibi igbafẹ lati da awọn eeyan laraya.

O ṣalaye pe kete tawọn araalu ta awọn lolobo pe Mr White ṣe pati onihooho ni opopona Joab, lẹyin ile itaja Shoprite, n’Ilọrin lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iwadii tọwọ fi tẹ afurasi naa.

Ọga ọlọpaa naa ni ohun ti afurasi ọhun atawọn ẹgbẹ rẹ to ti sa lọ ṣe naa ta ko ofin ati ilana Covid-19.

O ni awọn ti n ṣakitiyan lati mu awọn to sa lọ naa, lẹyin eyi ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.

Bakan naa, ọwọ ti tẹ afurasi meji; Umaru Mohammed Tambaya ati Muhammed Tambaya Bell, ara awọn ajinigbe to ji awọn ọmọ ilẹ Turkey mẹrin gbe loṣu keje, ọdun 2019, labule Gbugbu, nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara.

Bagega ni awọn afurasi ajinigbe tọwọ tẹ nigba tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lo darukọ awọn mejeeji tawọn fi bẹrẹ si i tọpinpin wọn ko too di pe wọn ko si pampẹ.

O nigba ti wọn gbero lati tun ji eeyan gbe lọwọ awọn tẹ wọn. O ṣalaye pe lasiko tawọn beere ọrọ lẹnu wọn, wọn jẹwọ pe loootọ lawọn wa lara awọn to ji awọn oyinbo ọmọ ilẹ Turkey gbe, wọn ni ọpọlọpọ awọn ijinigbe lawọn ti kopa nibẹ lọna Enugu si Abakaliki.

Ileeṣẹ ọlọpaa tun mu afurasi kan, Abbey Adeyẹye, ẹni ogoji ọdun, fẹsun jiji mọto gbe labule Gbugbu lọna Lafiagi.

Wọn ni ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Edwin Nwakanude lo fi to ọlọpaa leti lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021, pe wọn ji ọkọ Golf 3 oun ti nọmba rẹ jẹ; PTG 01 XA, niwaju ile oun.

Ọna Ndanaku si Isanlu, nipinlẹ Kogi, lọwọ ti tẹ ọkunrin naa pẹlu mọto ọhun. O jẹwọ pe ọkọ meji loun ti ji, toun si ti ta si Kogi.

Awọn ọlọpaa tun mu afurasi meji; Sunday Babatunde ati Adebisi Ọlatunde, tawọn mejeeji n gbe agbegbe Ibafo, nipinlẹ Ogun, fẹsun jija mọto gba.

Ọkọ Toyota Yaris kan ti nọmba rẹ jẹ; EPE 971 DY ni wọn ji gbe, ibi ti wọn ti fẹẹ ta a ni Ipata Ọlọjẹ, niluu Ilọrin, lọwọ ọlọpaa ti tẹ wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa naa sọ pe awọn afurasi naa jẹwọ pe ọwọ ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Adekọya Ayọdele lawọn ti ja a gba lagbegbe Ejigun Agbẹdẹ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply