Nigba ti awọn agbofinro fọwọ ṣikun ofin mu awọn afurasi agbebọn meji kan, Bashir Muhammed, ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Nasiru Salisu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, wọn jẹwọ pe awọn lawọn ṣeku pa awakọ ofurufu nni, Captain AbdulKarim Bala Na’Allah, to jẹ ọmọ Sẹnetọ Bala Na’Allah, ni Kaduna.
Boroboro bii ajẹ to jeewọ lawọn afurasi ọdaran naa n ṣalaye fawọn oniroyin nipa iwa odoro ti wọn hu ọhun lasiko tawọn ọlọpaa ipinlẹ Kaduna patẹ wọn faye ri.
Ṣe ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lawọn ika ẹda kan lọọ ṣeku pa Oloogbe AbdulKarim lọganjọ oru, ninu ile rẹ to wa laduugbo Malali, niluu Kaduna, nipinlẹ Kaduna.
Awọn afurasi ọdaran tọwọ tẹ yii jẹwọ pe awọn mẹta lawọn ṣiṣe buruku naa, awọn ọlọpaa ṣi n wa ẹni kẹta, ọwọ o ti i to o.
Bashir Mohammad ti wọn loun gan-an ni olori awọn oṣikapaniyan naa sọ pe ọna Rabah, nijọba ibilẹ Ariwa Kaduna loun n gbe, o ni awọn o kọkọ ni i lọkan lati pa oloogbe naa, ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lawọn fẹẹ ji gbe, kawọn si gba owo diẹ lọwọ rẹ, tabi ohun tawọn ba ri ninu ile oloogbe naa.
Afurasi ọdaran yii loun o mọ oloogbe naa ri tẹlẹ, oun kan maa n gborukọ baba ẹ ni.
“Emi o mọ oloogbe yii ri tẹlẹ o, mi o si ro pe mo ri i ri. Lọjọ kan, awa mẹta la n kọja lọ niwaju ile rẹ, emi (Bashir), DanKano, ati Usman, la ba ri mọto bọginni ti wọn paaki sinu ọgba oloogbe naa. DanKano lo ni ka pada waa ji ọkọ naa gbe.
“Lọjọ keji, ojo nla kan rọ lọwọ, inu ojo naa la de sile oloogbe yii, a fo fẹnsi wọle, a si gun ori orule ile rẹ, a fi irinṣẹ kan ta a mu dani yọ iṣo ti wọn fi kan paanu, a fẹsẹ da abẹsitọọsi wọn lu, la ba wọle.
Lẹyin tawa meji ti wọle, a ṣilẹkun fun ẹkẹta wa, DanKano, tori oun lo mu tọọṣi dani, to n tan’na fun wa.
O da bii pe oye ina tọọṣi ti oloogbe naa ri lo mu ko fura, bo ṣe ri wa, o fa nnkan kan yọ labẹ bẹẹdi ẹ, loun ati Usman ba wọya ija. Ibi to ti n ba wa ja, tawa naa n ba a fa a, ilẹ yọ ọ, o ṣubu, la ba sare fi okun aromiyọ ti wọn fi n sa aṣọ de e lọwọ ati lọrun, bi ko ṣe le sọrọ mọ niyẹn, a mu kọkọrọ mọto rẹ, a ba tiwa lọ.”
Afurasi keji, Nasiru Salisu, ni wọn pe oun si opuresọn naa ni, o loun o fi bẹẹ kopa ju pe oun tẹle wọn lọ, o ni adugbo Kawo, niluu Kaduna, loun n gbe.
Nigba ti wọn bi wọn leere bi wọn ṣe ṣe mọto ọhun si, wọn lawọn ta a ni, ipinlẹ Niger lawọn ta a si, miliọnu kan naira lawọn si ta a.
Salisu ni owo ti wọn pin foun gẹgẹ bii iye to kan oun, irẹsi loun fi ra, baagi irẹsi mẹtalelogun loun ra, ṣugbọn oun o ri irẹsi naa gbe dele, awọn kọsitọọmu ni wọn gba a silẹ lọwọ oun lọna.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Muhammad Jalige ti sọ pe awọn o ti i pari iwadii, bẹẹ lawọn ṣi n wa ẹnikẹta wọn ati awọn mi-in ti ọrọ kan. O ni tiwadii ba ti pari, awọn afurasi ọdaran naa yoo fẹnu fẹra bii abẹbẹ niwaju adajọ.