Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ẹsọ alaabo (NSCDC) ẹka ti ipinlẹ Kwara, mu Peter Ovie ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44), Abdulrahman Jamiu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), Muyideen Tiamiyu, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31), ati Adeleke Mathew, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), fẹsun pe wọn lọ ji irin ikọle ti ko din ni ọgọta (60) ko, ninu ọgba Fasiti ilu Ilọrin.
Agbẹnusọ ẹsọ alaabo (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, sọ fun ALAROYE pe, ọkọ Toyota (bus) ti nọmba ẹ jẹ AAA-338XM ni ikọ awọn gba mu to ko irin ikọle ti ko din ni ọgọta (60), to jọ eyi ti wọn ji ko ninu ọgba ile ẹkọ giga Fasiti ilu Ilọrin. Ọwọ tẹ wọn lẹyin ti awọn kan ta awọn lolobo.
O tẹsiwaju pe lẹyin iwadii ti awọn ṣe ni asiri tu pe Peter to jẹ ọkan lara awọn afurasi ọhun jẹ onimọ ẹrọ to n mọjuto iṣẹ akanse ti ileesẹ (Pako 21, Investment LTD) n ṣe ninu ọgba naa, to si lẹdi apo pọ pẹlu awọn meji to ku lati ja ileeṣẹ naa lole.
Awọn meji ti wọn jọ jale jẹwọ pe Peter lo ni kawọn waa ji irin naa ko, ki ọwọ palaba awọn too ṣegi.
Afọlabi ti waa sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju, lẹyin iwadii lawọn afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.