Faith Adebọla
Lọwọlọwọ bayii, ododo ko ti i foju han tan lori iṣẹlẹ ijinigbe to waye lọna Igboọra siluu Eruwa l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja pẹlu bi ọrọ awọn ọlọpaa atawọn araalu ṣe ta ko ara wọn lori iṣẹlẹ naa.
Ṣugbọn ninu ọrọ tawọn ara ilu Eruwa ati Igboọra ba ALAROYE sọ lori foonu lọjọ Ẹti, wọn ni loootọ lawọn agbebọn ji awọn arinrin-ajo gbe, koda, awọn ọlọpaa funra wọn ti gbọ si i.
Ọgbẹni Ọlanrewaju Ogedengbe ti i ṣe adari ẹgbẹ OPC ni gbogbo agbegbe Ibarapa ṣọ pe, “Lóòótọ́ ni, nibi kan bayii to jinna sibi ti awọn ọlọpaa maa n duro si ni wọn ti ji awọn eeyan yẹn gbe.”
“Awọn onimọ niluu Eruwa ni wọn lọọ sọ fawọn ọlọpaa pe awọn ri mọto kan loju ọna, wọn ro pe niṣe ni wọn ji mọto yẹn gbe ni, awọn ọlọpaa Eruwa si gbe e sinu teṣan wọn lati mọ boya ẹni to ni in maa yọju nigba to ba ya.
“Ẹyin igba yẹn lawọn onimọto pe awọn ọlọpaa pe wọn ji awọn ero inu mọto yẹn gbe ni.”
Amọ ṣa, ọga awọn OPC yii sọ pe oun ko mọ ẹnikẹni ninu awọn ero inu ọkọ ti wọn ji gbe lọ yii, oun ko si ti i gbọ pe awọn ajinigbe kan si awọn mọlẹbi awọn ero naa lati beere fun owo.
Pẹlu bo ṣe jẹ pe aarin Eruwa si Igboọra ni wọn sọ pe ijinigbe ọhun ti waye, akọroyin wa pe Olu Igboọra, Ọba Jimọh Ọlajide Titiloye, Kabiesi si sọ pe ko ti i si araalu kankan tọ fi ti oun leti pe wọn ji eeyan oun gbe.
Bo tilẹ jẹ pe iroyin mi-in ti tun pada fidi ẹ mulẹ pe eeyan meji ni wọn ji gbe lọna Eruwa dipo eeyan mejidinlogun ti gbogbo oniroyin ti n pariwo tẹlẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ yii, CP Ngozi Onadeko, sọ pe irọ gbuu niroyin naa, ko si ohun to jọ pe wọn ji ẹnikẹni gbe lagbegbe naa.
Bakan naa lagbenusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ sọ pe “Ko si ohun to jọ bẹẹ. Wọn lè ji eeyan gbe loootọ, ṣugbọn nipa iṣẹlẹ ijinigbe eleeyan mejidinlọgbọn (18) yii, ko si ohun to jọ ọ.
“Nigba ta a gbọ iroyin yẹn, a ṣewadii debii pe gbogbo garaaji to wa niluu Eruwa la lọ lati mọ boya awakọ kan ko ero lọdọ wọn ṣugbọn ti ko dari de, gbogbo wọn sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ lọdọ awọn.”