Irọ ni o, a o sọ pe kawọn banki maa gba owo Naira atijọ pada lọwọ araalu-CBN

Faith Adebọla, Eko

Ni iyatọ gedegede si ọrọ kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara ati laarin ilu pe banki apapọ ilẹ wa ti pero da, wọn ti ni kawọn banki yooku bẹrẹ si i gba awọn owo atijọ pada lọwọ awọn araalu, paapaa ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) ati ẹgbẹrun kan Naira (N1,000), banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria (CBN), ti kede pe ko sohun to jọ ọ o, wọn lawọn o sọ bẹẹ, awọn o si paṣẹ bẹẹ, wọn ni iroyin ofege ni, ki i ṣe ọdọ awọn lo ti wa.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii, eyi to tẹ Alaroye lọwọ ni wọn ti sọrọ ọhun. Alakooso ẹka ibanisọrọ fun banki apapọ ọhun, Ọgbẹni Osita Nwanisobi, lo buwọ lu atẹjade naa, to si fi i lede fawọn oniroyin.
Atẹjade ọhun ka pe:
“Iroyin ofege kan ti a ko fọwọ si, ninu eyi ti wọn ti sọ pe banki apapọ ilẹ wa ti paṣẹ pe kawọn ileefowopamọ bẹrẹ si i gba ẹẹdẹgbẹta Naira ati ẹgbẹrun kan Naira atijọ pada lọwọ araalu ti de etiigbọ wa.

“A o fẹ kẹyin eeyan mefo nipa ọrọ yii, ni ibamu pẹlu ọrọ ti Aarẹ Buhari ba araalu sọ lori redio ati tẹlifiṣan lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, igba Naira atijọ (N200) nikan ni wọn fun banki apapọ laṣẹ lati ko bọ sita, ka si pin in kiri faraalu lati na fun ọgọta ọjọ si i, eyi ti yoo dopin ni ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

“A rọ ẹyin araalu lati ma ṣe tẹti si ahesọ ati iroyin ofege eyikeyii to ba sọrọ nipa aṣẹ ti banki apapọ ko fọwọ si, tabi eyi to ta ko ipinnu ijọba apapọ lori ọrọ yii.

“A si rọ ẹyin oniroyin gbogbo, lati maa ṣayẹwo, kẹ ẹ si ṣewadii daadaa kẹ ẹ too bẹrẹ si i gbe iroyin kan jade, tori ẹnu onikan la a ti gbọ pọun-un o, a o si fẹ kẹ ẹ ṣi awọn araalu lọna.”
Bẹẹ ni atẹjade naa sọ.

Leave a Reply