Irọ ni, wọn ko mu Ẹniọla Badmus lori iku ọmọ Davido o!

Faith Adebọla

Awuyewuye to n lọ nigboro, paapaa lori ẹrọ ayelujara lasiko yii ni pe awọn ọlọpaa ti mu Ẹniọla Badmus, gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa tawọn eeyan mọ si Wule Bantu, tabi Gbogbo Big Gez, lori iku Ifeanyi, ọmọ ilumọ-ọn-ka olori taka-sufee nni, Davido. Ṣugbọn ko sootọ kankan ninu ọrọ yii, ko sẹni to mu Ẹniọla, ko sẹni to bi i leere ọrọ kankan, tori iku ọmọ naa ko kan an lọwọ lẹsẹ rara.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla yii, ni ọrọ naa bẹrẹ si i ja ran-in pe wọn ti mu Ẹniọla Badmus lori iku ọmọ Davido, wọn ni nani to wa lakolo ọlọpaa latari iṣẹlẹ yii ti sọ fawọn ọlọpaa pe Ẹniọla lo pe oun lori aago, ipe naa loun yẹba lati lọọ dahun, toun ko fi mọgba ti Ifeanyi sere lọ sibi odo iluwẹẹ atọwọda, iyẹn swimming pool, to wa layika ile naa, titi ti ewu fi wu ọmọkunrin ọhun.

Wọn tun ni Ẹniọla yii kan naa lo kọkọ gbe iroyin ibanujẹ iku ọmọ ọhun sori ikanni Instagiraamu rẹ, wọn leyii lo jẹ kawọn eeyan maa fi eeji kun ẹẹta lori ọrọ naa, tawọn ọlọpaa fi lọọ mu un.

Amọ ninu iwadii t’ALAROYE ṣe, ọlọpaa o mu Ẹniọla Badmus. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to ba akọroyin wa sọrọ lori aago lọjọ Satide sọ pe irọ ni, ko sohun to jọ ọ, awọn o mu oṣere tiata naa rara.

Bakan naa ni ẹnikan ti ko fẹ ka darukọ oun, amọ to jẹ ọrẹ timọtimọ pẹlu Ẹniọla sọ pe ko sootọ ninu ọrọ naa, ahesọ ati atamọ-mọ-atamọ ni. O ni ọlọpaa ko mu Ẹniọla Badmus o, ile rẹ lo wa, ko sohun to ṣe e.

Ọjọ Satide yii kan naa lawọn ọlọpaa gbe abajade iwadii ti wọn ṣe lori iku ọmọ ọhun, iyẹn iwadii tawọn agbofinro atawọn akọṣẹmọṣẹ iṣegun maa n ṣe si oku ki wọn le mọ’ru iku to pa a, tawọn oyinbo n pe ni autopsy, jade. Ibẹ si ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe niṣe ni Ifeanyi mu omi ku lasiko to ko sinu omi iluwẹẹ to wa ninu ile baba rẹ, ki i ṣe pe boya ẹnikẹni ṣe ohunkohun fun un, bẹẹ ni ejo iku naa ko lọwọ ninu rara.

 

Leave a Reply