Jọkẹ Amọri
Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti sọ pe oun kọ loun ni ilẹ tabi ile alaja mọkanlelogun to wo lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu yii, to si pa ọpọlọpọ eeyan.
Ninu atẹjade kan ti Agb ẹnusọ Ọṣinbajo lori eto iroyin, Laolu Akande gbe jade lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii lo ti sọrọ naa.
O salaye pe ahesọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni iroyin irọ ti awọn kan n gbe kiri pe Igbakeji Aarẹ lo ni ilẹ ati ile alaja mọkanlelogun to wo naa. Ọṣinbajo ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹo si jẹ iwa ika patapata pe awọn eeyan le maa fi iru ọrọ to ṣe pataki, to si mu ẹmi ọpọ eeyan lọ bayii ṣe oṣelu, ti wọn yoo si maa gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.
Ọṣinbajo ni oun kẹdun pẹlu awọn ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si, oun si ti jẹ ki gbogbo dukia ti oun ni di mimọ faye gbọ.
Laipẹ yii ni awọn iroyin ori ẹrọ ayelujara kan gbe epe Igbakeji Aarẹ lo ni ile naa, ati pe ọwọ gbajumọ oniṣowo mọto nni, Oloye Micheal Ade-Ojo lo ni ilẹ naa, oun lo si ta a fun Ọṣinbajo. Ṣugbọn baba naa ti ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lori ọrọ naa pe oun ko ta ilẹ kankan fun Ọjọgbọn Ọṣinbajo. O ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe loootọ loun ni ilẹ si agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, oun ko ta ilẹ naa, bẹẹ loun ko si ni i lọkan lati ta a fun ẹnikẹni. O ni ahesọ ti ko ridii mulẹ rara ni ohun tawọn eeyan n gbe kiri pe oun loun ni ilẹ ile alaja mọkanlelogun to wo naa, ati pe oun loun ta a fun ọjọgbọn Ọṣinbajo. O ni ko sohun to jọ bẹẹ rara,