Jamiu Abayọmi
Inu ayọ ati idunnu nla lawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn nipenija oju wa bayii latari bi Aarẹ orilẹ-ede yii, Bọla Ahmed Tinubu, ṣe buwọ lu pinpin gilaasi oju to le ni miliọnu marun-un lọfẹẹ fun gbogbo awọn tarun oju ba n yọ lẹnu lati ẹka eto ilera ijọba apapọ Naijiria pẹlu ajọṣepọ ajọ kan ti wọn ṣagbekalẹ eto kan to n jẹ Peak Vission.
Aarẹ ṣiṣọ loju ọrọ ọhun lasiko to n gbalejọ oludasilẹ ajọ kan ti wọn n pe ni Vission Catalyst Fund, iyẹn Ọjọgbọn Andre Bastawrous, nile ijọba, l’Abuja, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nibi ti Aarẹ ti sọ ninu ọrọ rẹ pe nnkan to wu oun lori, to si tun gun oun ni kẹṣẹ lati fọwọ si eto naa lawọn iriri toun paapaa ti ni lori ọrọ oju lati ọdọ iya oun.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale, fi lede lo ti sọ sibẹ bayii pe, “Iriri mi ti ọdọ iya mi wa, ki Ọlọrun dẹ ilẹ fun un, o ṣe aisan kan nigba to wa laye to ṣe pe ko le ri mi, ọpẹlọpẹ itọju to peye ti a ṣe fun un, to si gba gilaasi lo too le riran ri mi kedere.
“Ibeere ti iya naa kọkọ bi mi ni pe: nitori pe mo ni ẹ lo ṣe ṣe eleyi fun mi, kin-ni yoo ṣẹlẹ si awọn iya agbalagba bii temi ti wọn ni iru ipenija bayii, ti ko si si ẹni ti yoo ṣe itọju bayii fun wọn?
“Lati igba naa ni mo ti ṣe ileri fun un pe ma a ṣeto ayẹwo ati iwosan ọfẹ fun awọn to ni ipenija oju, paapaa bi mo tun ṣe ri bi iya naa ṣe fẹ ki awọn to wa ni iru ipo tirẹ naa riran pada, nigba naa la ṣe eto gilaasi ọfẹ fun ọpọlọpọ miliọnu olugbe ipinlẹ Eko, gbogbo aye naa lo si ri i bi inu awọn to jẹ anfaani eto naa ṣe dun to’’.
Aarẹ Tinubu ni awọn ogbontarigi ti wọn datọ lẹnu igbin lẹka eto ilera, ti ọpọ ninu wọn si ti fakọ yọ nidii iṣẹ naa ni yoo ṣamojuto rẹ.