Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Majistreeti kan to filu Ilọrin ṣe ibujokoo ti paṣẹ pe ki wọn fi ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan torukọ ẹ n jẹ Adamu AbdulGaniyu, sẹwọn titi di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, ti igbẹjọ rẹ yoo maa tẹsiwaju. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o fẹẹ fipa ba ọmọ kekere, ẹni ọdun mẹta, to n kọ ni kewu lo pọ lagboole Ajíjọlá Ànábì, lagbegbe Ìta-Kúdíimá, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe iya ọmọdebinrin yii, iyẹn Mariam Zakariyau, lo mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Ọjà-Ọba, niluu Ilọrin, pe Adamu AbdulGaniyu, to n kọ ọmọ oun ni kewu fọgbọn tan an wọnu yara rẹ, o bọ pata ẹ kalẹ, o si sun le e lori. O tẹsiwaju pe nigba ti AbdulGaniyu re kọja niwaju ṣọọbu iya ọmọde yii ni ẹru bẹrẹ si i ba a, to si pada sọ fun iya rẹ pe ṣe ni afurasi mu oun lọ si yara rẹ, o bọ pata nidii oun, lẹyin to bọ oun sihooho lo ni ki sun lori ẹni, to si ṣun le oun lori.
Bo tilẹ jẹ pe ayẹwo ti wọn ṣe fun ọmọbinrin yii nileewosan fihan pe ara rẹ ṣi wa lodidi, ṣugbọn adajọ tun taari aafaa yii ṣọgba ẹwọn.
Agbefọba, Inspẹkitọ Innocent Owoọla, rọ kootu pe ki wọn ṣi fi AbdulGaniyu pamọ sẹwọn titi toun yoo fi gba imọran lati ọdọ ẹka to n gba kootu nimọran lori ẹsun bii eyi. Atotonu ti afurasi to n jẹjọ naa si ṣe lati ta ko eyi ko ta leti adajọ rara.
Adajọ Ibrahim Dasuki to gbọ ẹsun naa paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ sẹwọn titi digba ti imọran yoo fi de, ibẹ ni yoo wa titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.