Faith Adebọla, Eko
‘Koro wa o, koro is real, koro lo pa ẹgbọn mi o, ẹni ba n sọ pe ko si koro, irọ ni tọhun n pa o. Mo bẹ yin kẹ ẹ waa maa lọ ile yin. Ijẹbu la maa sin wọn si, mo si rọ yin pe kẹ ẹ ma ṣopo ni ẹ n bọ fun isinku lọla, adura ni kẹ ẹ saa maa fi ranṣẹ si oloogbe, a dupẹ lọwọ yin.’
Iwọnyi ni diẹ ninu ọrọ aro ti ẹnikan to pera ẹ ni ẹgbọn fun agba oṣelu Eko ati ọkan lara awọn aṣọfin agba l’Abuja, Senetọ Adebayọ Sikiru Ọshinọwọ, to ku lojiji lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii. Oun lo n ṣoju ẹkun-idibo Ila-Oorun Eko nile aṣofin ọhun.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii ọjọ mẹsan-an sẹyin ni Ọshinọwọ ṣaroye pe ara oun ko ya, wọn ni iba ati otutu ni wọn kọkọ ro pe o n ṣe e. Nigba ti awọn oogun to lo nile ko fẹẹ ran kinni ọhun ni wọn gbe e lọ si ibi ayẹwo awọn alarun aṣekupani Koronafairọọsi to wa ni Yaba.
Wọn ni nigba ti aarẹ naa ko fẹẹ gboju ọwọ ni wọn gbe e lọ si ọsibitu First Cardiology Consultants, lagbegbe Ikoyi, lerekuṣu Eko. Ileewosan naa la gbọ pe o pada ku si.
Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan n sọ nile sẹnetọ naa to wa ni Ogudu GRA, nigba ti akọroyin wa ṣabẹwo sibẹ lọsan-an ọjọ iṣẹlẹ ọhun. Ọpọ awọn to wa sibẹ lo daro iku agba ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn tun mọ si Pepperito ọhun. Wọn ni ẹlẹyinju-aanu ati oloore awọn ni. Bẹẹ lawọn kan n leri pe iku rẹ yii maa lẹyin ninu eto oṣelu ipinlẹ Eko, wọn ni awọn gbagbọ pe wọn pa ọkunrin naa ni, wọn ni ija oṣelu kan to n lọ labẹnu laarin ẹgbẹ APC l’Ekoo wa lara ohun to mu ẹmi ẹ lọ yii.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni Oloogbe Ọshinọwo, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1955, ni wọn bi i si agbegbe kan ti wọn n pe ni Odo-Egbo, ni ilu Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun.
Ileewe alakọọbẹrẹ Saint Augustin, n’Ijẹbu-Ode, lo lọ, o si lọọ ka ẹkọ girama rẹ ni ileewe sẹkọndiri to wa niluu Isọyin, ni Ijẹbu. Lẹyin naa lo lọọ kawe ẹkọ imọ ile-kikọ nileewe kkan niluu Rome, lorileede Italy, o si tun gba oye masita ni Yunifasiti Urbaniana, niluu naa.
Nigba to pada si Naijiria ni 1977, o ṣiṣẹ ni ẹka ileeṣẹ ode tijọba apapọ (Federal Ministry of Works) o si goke agba di ọkan lara awọn darẹkitọ ẹka naa.
Oloogbe Ọshinọwọ bẹrẹ irinajo oṣelu rẹ nigba ti wọn yan an gẹgẹ bii alaga awọn ọdọ ninu ẹgbe oṣelu Social Democratic Party (SDP).
Lọdun 2003, o dije, o si wọle sipo aṣofin to ṣoju ijọba ibilẹ Kosọfẹ nileegbimọ aṣofin Eko, ki wọn too yan an sipo aṣofin agba lọdun 2019, ipo naa lo si wa tiku fi de yii.
Senatọ Adebayọ Ọshinọwọ fẹ Abilekọ Mariam Ayọdele Ọshinọwọ, o si bimọ mẹta. Lara awọn ọmọ naa ni Dokita Taiwo Bakare, Dokita Kehinde Adebisi ati Babatunde Ọshinọwọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọla, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni eto isinku rẹ waye n’Ijẹbu-Ode.