Adewale Adeoye
‘‘Ki i ṣe asọdun mọ pe iru ẹgbẹ oṣelu APC to lagbara gidi bayii lo gbọdọ maa ṣakoso awọn ipinlẹ gbogbo lorileede yii, a n mu ẹyẹ bọ lapo ni, a maa too gba akoso ijọba awọn ilẹ Ibo naa, a maa gbajọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu APGA to n ṣe e lọwọ bayii.
O waa rọ awọn agba ẹgbẹ naa gbogbo pe ki wọn ma ṣe sun asunpiye lori aṣeyọri kekere ti wọn ni nipinlẹ Edo yii, ki wọn maa ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe gbogbo ibi atawọn ipinlẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ko gba ni wọn gba mọ awọn alatako wọn lọwọ pata.
‘‘A ti n ṣiṣẹ labẹnu bayii lati gbajọba ipinlẹ Anambra, ọdun to n bọ ni ibo sipo gomina ipinlẹ naa maa waye, a ni eto kan ta a n ṣe bayii, a fẹẹ gba awọn ipinlẹ maraarun to wa nilẹ Ibo ni, meji lo wa lọwọ wa bayii, o kere sohun ta a fẹẹ ṣe, a maa gba meji si i, bo ba maa fi di asiko ibo gbogbogboo iyẹn lọdun 2027, yoo le rọrun fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati bori ninu ibo ti wọn ba dije fun.’’
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Alhaji Abdullah Ganduje, lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n ki awọn oloye ẹgbẹ APC nipinlẹ Edo ku oriire ti aṣeyọri ti wọn ṣe lasiko ibo naa niluu Abuja.
O sọ pe gbogbo ohun to ba gba pata lawọn maa lo lati ri i pe ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Ondo, to n bọ lọna yii, o ni iru ọgbọn ati ilana tawọn gba lati jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Edo to waye laipẹ yii lawọn maa lo lasiko ibo Ondo to n bọ lọna yii.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ibo sipo gomina ipinlẹ Ondo maa waye, Alaga ẹgbẹ oselu APC, to tun ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ si ti ṣeleri pe ọna tawọn gba lati jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Edo to waye laipẹ yii lawọn maa lo lati fi bori awọn alatako ninu ibo naa bayii.