Iru ibunu wo ree, nitori ọrọ ti ko to nnkan, Fraiday gun ọrẹ ẹ pa

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọdọ awọn ni Ọgbẹni Friday Nku, ẹni ọdun mẹtalelogoji, to gun ọrẹ ẹ, Oloogbe John Musa, ẹni ọdun mejidinlogoji lọbẹ pa wa. ALAROYE gbọ pe ọrọ kan lo ṣe bii ọrọ laarin Friday ati oloogbe naa l’Ọjọruu, Wesidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ to ṣẹṣẹ pari yii, kawọn eeyan to wa nitosi si too mọ ohun to n ṣẹlẹ laarin wọn, Friday ti fọbẹ oloju meji kan to wa lọwọ rẹ gun ọrẹ rẹ ọhun pa.

Atejade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọlọla Odutọla, fi sita nipa iṣẹlẹ naa lọjọ Eti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, ni pe Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ to kọja yii, niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ laduugbo kan ti wọn n pe ni Ọmọlara, niluu Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

Alukoro ni, ‘‘A ko mọ ohun to ṣokunkun iṣẹlẹ naa rara. Ohun ta a gbọ ni pe ede aiyede kekere kan lo bẹ silẹ laarin awọn mejeeji, ti Friday si fọbẹ gun ẹnikeji rẹ pa. Gbara to ṣẹlẹ lawọn kan tọrọ ọhun ṣoju wọn ti sare gbe e lọ si ọsibitu kan to wa nitosi, ṣugbọn awọn dokita sọ pe o ti ku ki wọn too gbe e de ọdọ awọn.

‘‘ A ti gbe oku oloogbe naa lọ si ọsibitu kan lati ṣayẹwo si i, ka le mọ ohun to pa a’’.

Awọn ọlọpaa lawọn n duro de esi ayẹwo tawọn lọọ ṣe si oloogbe naa lara, lẹyin naa lo ni awọn maa foju afurasi ọdaran yii bale-ẹjọ.

Leave a Reply