Faith Adebọla
Inu ibanujẹ gidi, adanu ọna meji ni baale ile kan, Taiwo Fayọbi wa bayii niluu Ikẹnnẹ, nipinlẹ Ogun, latari bawọn olubi ẹda kan ti wọn fura pe o ṣee ṣe ko jẹ adigunjale ṣe ji ọkọ rẹ gbe, bẹẹ ọmọ rẹ, ọmọ irinsẹ tọjọ ori rẹ ko ju ọdun mẹta lọ wa ninu ọkọ ti wọn wa lọ tefetefe ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ buruku ọhun.
O ni Taiwo Ọlọnade ati ọmọ rẹ ọhun ni wọn jọ n bọ lati ode kan laaarọ ọjọ naa, oun funra rẹ lo wa mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry ti nọmba rẹ jẹ PKA 446 GV naa bọ, ọmọọwọ naa sun sori ijokoo ẹyin, bo si ṣe de ẹnu geeti ile wọn lo bọọlẹ, amọ ko pana ọkọ, o kan ni k’oun lọọ ṣi geeti ko le wa ọkọ naa wọle, nibi to ti n gbiyanju lati ṣi geeti lawọn janduku meji kan ti yọ latinu igbo, boya wọn ti lugọ de e tẹlẹ ni o, boya o si ṣe kongẹ wọn ni, ko sẹni to ti i le sọ, kia lawọn gende naa bẹ sinu ọkọ ayọkẹlẹ ọhun, ọkan jokoo saaye dirẹba, ni wọn ba tẹna ọkọ siwaju, afi bii mọnamọna, wọn wa ọkọ ayọkẹlẹ naa lọ pẹlu ọmọọlọmọ to wa ninu rẹ.
Gbogbo ariwo ati iboosi ti Taiwo lọ ko seeso rere kan tori kawọn aladuugbo too jade lati gbọ ohun to ṣẹlẹ, ẹfọn ti fẹ.
Titi ta a fi n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to gbọ ‘mo ko o’ ọkọ ayọkẹlẹ naa, ati ọmọ to wa ninu rẹ, amọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ti parọwa sawọn araalu lati ṣeranwọ, ti ẹnikẹni ba kẹẹfin ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry ti nọmba rẹ jẹ PKA 446 GV, ki wọn tete fi to awọn agbofinro eyikeyii to ba wa nitosi leti, lati doola ẹmi ọmọ naa.