Iru ki waa leleyii! Erinmilokun pa alaboyun kan

Monisọla Saka

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni obinrin alaboyun kan nipinlẹ Benue, ṣe bẹẹ kagbako iku ojiji  lẹyin ti Erinmilokun kan ṣeku pa a lori afara atijọ odo Benue, to wa niluu Makurdi, olu ilu ipinlẹ naa.

Afara igbalode nla ti wọn n pe ni biriiji yii, oriṣii meji ẹ lo wa lori alagbalugbu omi naa, afara ti atijọ ati tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe.

Gẹgẹ bi akọroyin The Nation, ṣe ṣalaye, o ni erekusu omi yii ni alaboyun ọhun pẹlu awọn ontaja yooku lọ lati lọọ ra ẹfọ ti wọn n tun ta laarin ilu. Lasiko ti wọn wa nibi ti wọn ti n raja leti omi naa naa ni wọn ni Erinmilokun ọhun ṣadeede ja wa lati inu omi, to si lọọ fibinu kọ lu obinrin alaboyun naa.

Oju-ẹsẹ ni wọn fi ọkọ oju omi igbalode kekere to maa n lo ẹnjinni, (ferry) gbe obinrin tẹnikẹni ko mọ ile tabi ọna rẹ yii, ki wọn le lọọ tọju rẹ. Ṣugbọn afi bii eedi lọrọ naa, nitori aarin agbami ni wọn wa ti ọkọ oju omi yii fi taku. Ni wọn ba tun gbe obinrin naa sinu ọkọ oju omi onigi.

Afi bi ẹranko buburu yii ṣe tun lọọ kọ lu ọkọ oju omi oni pako ti wọn tun gbe obinrin yii si, tiyẹn si lọọ fori sọ nnkan. Niṣe lo fọ si  wẹwẹ, nibẹ ni obinrin alaboyun ti wọn n gbiyanju lati du ẹmi rẹ yii si ti re somi, to si ṣe bẹẹ ri wọ isalẹ omi lọ.

Lọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ṣa awọn eeyan kan jọ, ti wọn si wa oku obinrin naa jade.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue, SP Sewuese Anene, ni pe ileeṣẹ awọn ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply