Iru ki waa leleyii! Lẹyin oṣu mẹrin tọkunrin yii gbeyawo lo pokunso

Monisọla Saka

Inu ọfọ nla ni awọn ẹbi iyawo tuntun kan ati ọkọ ẹ to n jẹ Usman Sanigoga, ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun (30), to n gbe lagbegbe Akula Quarters, ijọba ibilẹ Babura, nipinlẹ Jigawa, wa bayii, pẹlu bi ọkunrin naa ṣe fi iku gbigbona pa ara rẹ lẹyin oṣu mẹrin to segbeyawo.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Adamu Shehu, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ aabo ara ẹni laabo ilu, sifu difẹnsi (NSCDC) ṣe sọ, l’Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, niluu Dutse, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa. O ni ko pẹ pupọ tọkunrin naa ṣegbeyawo lo ṣadeede pokunso.

O ṣalaye pe ni l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni gẹrẹ tiyawo Sanigoga wọle de lati ibi to lọ lo ba ọkọ ẹ to n rọ dirodiro loke aja ninu yara wọn.

Oloogbe, to jẹ akọṣẹmọṣẹ ayaworan, ni wọn lo gbe iyawo ẹ lọ sọdọ awọn mọlẹbi ẹ kan ni nnkan bii aago meji ọsan Ọjọruu yẹn naa, to si ṣeleri fun un pe oun n pada bọ waa gbe e nirọlẹ.

Igba tiyawo reti titi ti ko ri i lo pe foonu ẹ, ṣugbọn ti ko gbe e pẹlu bo ṣe pe e ni aimọye igba to. Bi ko ṣe gburoo ọkọ ẹ rara yii lo mu ko sare gbe ọkada pada sile.

Shehu ni, “Obinrin yẹn ni titi pa loun ba ilẹkun ile awọn, ọlọkada to gbe e wa sile lo si bẹ pe ko ba oun fo fẹnsi wọle lati le ba a ṣilẹkun ẹnu ọna.

Nnkan akọkọ to fu obinrin naa lara ni ọna ti wọn gba paaki ọkada ọkọ ẹ, o yatọ gedegede si aaye ti ọkọ ẹ maa n gbe e si ati bo ṣe maa n paaki rẹ.

“Jannajanna ni obinrin naa sa wọle, nnkan to ba pade ninu ile naa si ka a laya debii pe niṣe lo daku lọ rangbọndan lẹyin to ri oku ọkọ ẹ to ti pokunso, to n rọ dirodiro loke.

Ọlọkada to gbe e wa yii ni Ọlọrun fi ṣe angẹli rẹ, ọkunrin naa lo kegbajare sawọn aladuugbo ti wọn sare yọju sibẹ.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti gbe ọkunrin naa lọ sileewosan, ṣugbọn awọn dokita ṣalaye pe oku ni ẹni ti wọn gbe wa”.

O tẹsiwaju pe, bo tilẹ jẹ pe awọn to sun mọ oloogbe naa sọ pe ipenija ọpọlọ maa n sọ ọkunrin naa wo lẹẹkọọkan, ati pe oṣu mẹrin sẹyin ni tọkọ-taya naa ṣegbeyawo, ti wọn si ti n gbe ninu ayọ ati alaafia, ko too di pe iṣẹlẹ buburu naa waye.

O ni ninu iwadii ti ajọ sifu difẹnsi ṣe ni wọn ti ri i pe séèfù (drawer) kan to wa lẹgbẹẹ bẹẹdi yara wọn ni ọkunrin naa gbe sori bẹẹdi nla wọn, to fi ribi ga de oke aja to so okun to fi para ẹ si.

A gbọ pe wọn ti sin oloogbe naa nilana ẹsin Musulumi, ṣugbọn ajọ NSCDC ṣi n ba iwadii lọ lori iku abami tọkunrin naa ku.

Leave a Reply