Iru ki waa leleyii, ọkọ tẹ ọlọkada kan pa l’Óbòtò

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọlọkada kan ti  pade iku ojiji loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ, laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kejila, ọdun ta a wa yii.

Awakọ Toyota Corolla kan lo tẹ ẹ pa loju ọna tirẹ to n gba lọ lagbegbe Òbòtò, eyi to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo.

ALAROYE gbọ lati ẹnu awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn pe ọna Ondo ni awakọ Corolla naa ti n bọ, nigba ti ọlọkada n bọ lati abule kan ti wọn n pe ni Omilúri, eyi to to bii ibusọ mẹta sibi ti ijamba yii ti waye.

Asiko ti awakọ ọhun fẹẹ sare ya ọkọ kan to wa niwaju rẹ silẹ pẹlu ere buruku to n sa lo lọọ kọ lu ọkunrin ọlọkada to n bọ loju ọna tirẹ jẹẹjẹ.

Loju ẹsẹ lọkunrin ti wọn lo jẹ ọmọ bibi ilu Calabar, nipinlẹ Cross River, naa ti ku pẹlu bi wọn ṣe ni ọkọ ọhun run oun ati ọkada rẹ jegejge mọ ẹgbẹ oju ọna to tẹ ẹ pa si.

Ni asiko ti akọroyin wa debi iṣẹlẹ ọhun, gbogbo ohun to ku lara ọkada Honda naa ko ju taya ẹyin ati férémù rẹ lọ, nigba ti imu ọkọ Toyota ọhun naa fẹrẹ parẹ tan ninu igbo ibi to fori sọ.

Ohun ta a gbọ ni pe kiakia ni awakọ ọhun ti sa kuro nibi iṣẹlẹ naa nitori ibẹru, to si lọọ fa ara rẹ le awọn ọlọpaa ilu Bọlọrunduro, lọwọ. Awọn ẹṣọ ojupopo ni wọn pada waa gbe oku ọlọkada naa kuro nibẹ, ti wọn si lọọ tọju rẹ pamọ si mọsuari ọsibitu ijọba to wa niluu Ondo.

Ohun ta a gbọ lẹnu awọn to mọ oloogbe ọhun daadaa ni pe iṣẹ ọdun lo waa ṣe lọdọ ẹni to gba a tira labule Omilúri, ọsẹ bii meji si asiko ta a wa yii ni wọn lo si fẹẹ pada siluu abinibi rẹ nipinlẹ Cross River, lẹyin to ti sin ọga rẹ fun odidi ọdun kan gbako.

Leave a Reply