Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Epe rabandẹ rabandẹ lawọn eeyan ti wọn ri oku gende kan ti awọn ọbayejẹ to ṣee ṣe ko jẹ afini-ṣetutu kun bii ẹran, ti wọn ge ori ati ọwọ re lọ, ti wọn si wọ gbunduku ara baale ile naa sinu kanga.
Baale ile ọhun ti ko sẹni to da a mọ ni wọn ba oku ẹ ninu kanga kan lagbegbe Olókońlá, Wáráh, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun, Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Awọn ti wọn ri oku naa ni wọn gbe e jade ninu kanga, iyalẹnu lo si je fun wọn nigba ti wọn gbe e jade ti ko si ori ati apa kan lara rẹ mọ.
Awọn olugbe agbegbe naa sọ fun awọn oniroyin pe laaarọ kutu ti awọn ọmọ ileewe Sẹkọndiri agba ni Wáráh (Wáráh Community Senior Secondary School), fẹẹ pọn omi ninu kanga ti wọn ri oku baale naa ni wọn figbe ta, eyi lo sokunfa bi gbogbo adugbo ṣe mọ.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe awọn n gbọ ariwo loru mọju ninu igbo kan to sun mọ agbegbe naa, sugbọn ko sẹni to le jade sita lọjọ buruku yii, nitori niṣe ni ibẹrubojo gbilẹ lọkan awọn eeyan lọjọ naa, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun to n sẹlẹ. Afi nigba ti ilẹmọ tawọn ọmọọleewe fẹẹ pọmi nibi kanga na ti wọn ri oku ti wọn ti ge ori ati ọwọ kan rẹ lọ yii.
Alaga agbegbe Wáráh, Alaaji Salman AbdulQadir, ṣalaye fawọn oniroyin pe iṣẹlẹ naa jọ ni loju, to si ka ni laya pẹlu, tori pe awọn ko ri iru iṣẹlẹ kayeefi bayii ri lagbegbe naa lati igba ti aye ti n wa. O tẹsiwaju pe awọn igi kaṣu lo yi agbegbe ibi ti wọn ti pa arakunrin yii ka, eyi to jẹ ko rọrun fawọn oniṣẹ buruku naa lati pitu ọwọ wọn. O rọ ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ isejọba Gomina AbdulRazaq, lati gbe agọ ọlọpaa kan wa si agbegbe naa ki eto aabo le gbopọn si i, ti awọn olugbe agbegbe naa yoo si le maa sun oorun asun fori le osuka.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, SP Ajayi Ọkasanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni wọn ti gbe oku arakunrin naa kuro nibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹ, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti n ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa.